Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 16:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

2. “Ìwọ ọmọ eniyan, fi nǹkan ìríra tí Jerusalẹmu ń ṣe hàn án,

3. kí o sì sọ fún un pé, OLUWA Ọlọrun sọ nípa Jerusalẹmu pé:“Ilẹ̀ Kenaani ni a bí ọ sí; ibẹ̀ ni orísun rẹ. Ará Amori ni baba rẹ ará Hiti sì ni ìyá rẹ.

4. Bí wọn ṣe bí ọ nìyí: nígbà tí wọ́n bí ọ, wọn kò dá ìwọ́ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi omi wẹ̀ ọ́. Wọn kò fi iyọ̀ pa ọ́ lára, wọn kò sì fi aṣọ wé ọ.

5. Ẹnikẹ́ni kò wò ọ́ lójú, kí ó ṣàánú rẹ, kí ó ṣe ọ̀kan kan ninu àwọn nǹkan wọ̀n-ọn-nì fún ọ. Ṣugbọn wọ́n gbé ọ sọ sinu pápá, nítorí pé wọ́n kórìíra rẹ ní ọjọ́ tí wọ́n bí ọ.

6. “Bí mo tí ń rékọjá lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, mo rí ọ tí ò ń ta ẹsẹ̀ ninu ẹ̀jẹ̀. Bí o tí ń yí ninu ẹ̀jẹ̀, mo bá sọ fún ọ pé kí o yè,

7. kí o sì dàgbà bí irúgbìn oko. Ni o bá dàgbà, o ga, o sì di wundia, ọyàn rẹ yọ, irun rẹ sì hù, sibẹ o wà ní ìhòòhò.

8. “Ìgbà tí mo tún kọjá lọ́dọ̀ rẹ, tí mo tún wò ọ́, o ti dàgbà o tó gbé. Mo bá da aṣọ mi bò ọ́, mo fi bo ìhòòhò rẹ. Mo ṣe ìlérí fún ọ, mo bá ọ dá majẹmu, o sì di tèmi. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

9. “Lẹ́yìn náà, mo mú omi, mo wẹ̀ ọ́; mo fọ ẹ̀jẹ̀ kúrò lára rẹ, mo sì fi òróró pa ọ́ lára.

10. Mo wá wọ̀ ọ́ ní aṣọ tí wọ́n ṣe ọnà sí lára, mo wọ̀ ọ́ ní bàtà aláwọ. Mo wọ̀ ọ́ ní aṣọ funfun, mo sì dá ẹ̀wù siliki fún ọ.

11. Mo ṣe ọ́ lọ́ṣọ̀ọ́, mo fi ẹ̀gbà sí ọ lọ́wọ́; mo sì fi ìlẹ̀kẹ̀ sí ọ lọ́rùn.

12. Mo fi òrùka sí ọ nímú, mo fi yẹtí sí ọ létí, mo sì fi adé tí ó lẹ́wà dé ọ lórí.

13. Bẹ́ẹ̀ ni mo fi wúrà ati fadaka ṣe ọ̀ṣọ́ sí ọ lára. Aṣọ funfun ati siliki tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ni mo dá fún ọ. Ò ń jẹ burẹdi tí ó dùn, tí wọ́n fi ìyẹ̀fun tí ó kúnná ṣe, ò ń lá oyin ati òróró; o dàgbà, o sì di arẹwà, o dàbí Ọbabinrin.

14. Òkìkí ẹwà rẹ wá kàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè; o dára nítorí pé èmi ni mo fún ọ ní ẹwà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. “Ṣugbọn o gbójú lé ẹwà rẹ; o di alágbèrè ẹ̀sìn nítorí òkìkí rẹ, o sì ń bá gbogbo àwọn eniyan tí wọn ń kọjá ṣe àgbèrè.

16. O mú ninu àwọn aṣọ rẹ, o fi ṣe ojúbọ aláràbarà, o sì ń ṣe àgbèrè ẹ̀sìn níbẹ̀. Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kò ṣẹlẹ̀ rí, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ṣẹlẹ̀ mọ́.

Ka pipe ipin Isikiẹli 16