Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 14:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní,

13. “Ìwọ ọmọ eniyan, bí orílẹ̀-èdè kan bá ṣẹ̀ mí, tí wọ́n ṣe aiṣootọ, tí mo bá run gbogbo oúnjẹ wọn, tí mo mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà, tí mo sì run ati eniyan ati ẹranko inú rẹ̀,

14. bí àwọn ọkunrin mẹta wọnyi: Noa, Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà ninu rẹ̀, ẹ̀mí wọn nìkan ni wọn óo lè fi òdodo wọn gbàlà. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.

15. “Bí mo bá jẹ́ kí àwọn ẹranko burúkú já wọ orílẹ̀-èdè náà, kí wọ́n pa wọ́n lọ́mọ jẹ, tí wọ́n sọ ilẹ̀ náà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò lè gba ibẹ̀ kọjá mọ́, nítorí àwọn ẹranko tí wọ́n wà níbẹ̀,

16. bí Noa, ati Daniẹli ati Jobu bá tilẹ̀ wà níbẹ̀, bí èmi OLUWA Ọlọrun fi ara mi búra pé, wọn kò ní lè gba ọmọkunrin tabi ọmọbinrin wọn là. Ara wọn nìkan ni wọn yóo lè gbàlà, ilẹ̀ náà yóo sì di ahoro.

Ka pipe ipin Isikiẹli 14