Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 13:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Wọn kò gun ibi tí odi ti lanu lọ, kí wọn tún un mọ yípo agbo ilé Israẹli, kí ó má baà wó lulẹ̀ lọ́jọ́ ìdájọ́ OLUWA.

6. Wọ́n ń sọ̀rọ̀ èké, wọ́n ń woṣẹ́ irọ́, wọ́n ń wí pé, ‘OLUWA wí báyìí.’ Bẹ́ẹ̀ sì ni OLUWA kò rán wọn níṣẹ́ kankan; sibẹ wọ́n ń retí pé kí OLUWA mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ.

7. Ǹjẹ́ ìran èké kọ́ ni wọ́n ń rí, tí wọ́n sì ń woṣẹ́ irọ́, nígbàkúùgbà tí wọn bá wí pé, ‘OLUWA wí báyìí’, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé n kò sọ̀rọ̀?”

8. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “Nítorí ọ̀rọ̀ asán tí ẹ̀ ń sọ, ati ìran èké tí ẹ̀ ń rí, mo lòdì si yín. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA Ọlọrun sọ.

9. N óo jẹ àwọn wolii tí wọn ń ríran èké níyà ati àwọn tí wọn ń woṣẹ́ irọ́. Wọn kò ní bá àwọn eniyan mi péjọ mọ́, tabi kí á kọ orúkọ wọn mọ́ ilé Israẹli, tabi kí wọ́n wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Ẹ óo sì mọ̀ pé èmi ni OLUWA Ọlọrun.

10. “Nítorí pé wọ́n ti ṣi àwọn eniyan mi lọ́nà wọ́n ń wí fún wọn pé, ‘Alaafia’ nígbà tí kò sí alaafia. Ati pé nígbà tí àwọn eniyan mi ń mọ odi, àwọn wolii wọnyi ń kùn ún ní ọ̀dà funfun.

11. Wí fún àwọn tí wọn ń kun odi náà ní ọ̀dà pé, òjò ńlá ń bọ̀, yìnyín ńlá yóo bọ́, ìjì líle yóo jà.

12. Nígbà tí odi náà bá wó, ǹjẹ́ àwọn eniyan kò ní bi yín pé, ‘Ọ̀dà funfun tí ẹ fi ń kun ara rẹ̀ ńkọ́?’ ”

13. Nítorí náà, OLUWA Ọlọrun ní, “N óo fi ibinu mú kí ìjì líle jà, n óo fi ìrúnú rọ ọ̀wààrà òjò ńlá, n óo mú kí yìnyín ńláńlá bọ́ kí ó pa á run.

14. N óo wó ògiri tí ẹ kùn lẹ́fun, n óo wó o lulẹ̀ débi pé ìpìlẹ̀ rẹ̀ yóo hàn síta. Nígbà tí ó bá wó, ẹ óo ṣègbé ninu rẹ̀. Ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

Ka pipe ipin Isikiẹli 13