Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 11:5-21 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Ẹ̀mí OLUWA bá bà lé mi, ó sọ fún mi, pé, “OLUWA ní, Èrò yín nìyí, ẹ̀yin ọmọ Israẹli, mo mọ ohun tí ẹ̀ ń rò lọ́kàn,

6. Ẹ ti pa ọpọlọpọ eniyan ní ààrin ìlú yìí; ẹ sì ti da òkú wọn kún gbogbo ìgboro ati òpópónà ìlú.

7. “Nítorí náà, àwọn òkú yín tí ẹ dà sí ààrin ìlú yìí ni ẹran, ìlú yìí sì ni ìkòkò, ṣugbọn n óo mu yín kúrò láàrin rẹ̀.

8. Idà ni ẹ̀ ń bẹ̀rù, idà náà ni n óo sì jẹ́ kí ó pa yín. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo wí bẹ́ẹ̀.

9. N óo ko yín kúrò ninu ìlú yìí, n óo sì ko yín lé àwọn àjèjì lọ́wọ́. N óo sì ṣe ìdájọ́ yín.

10. Idà yóo pa yín, ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín; ẹ óo wá mọ̀ pé èmi ni OLUWA.

11. Ìlú yìí kò ní jẹ́ ìkòkò fun yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò ní jẹ́ ẹran ninu rẹ̀; ní ààlà ilẹ̀ Israẹli ni n óo ti ṣe ìdájọ́ yín.

12. Ẹ óo mọ̀ pé èmi ni OLUWA; nítorí pé ẹ kò rìn ninu ìlànà mi, ẹ kò sì pa òfin mi mọ́, ṣugbọn ẹ ti gba àṣà àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n yi yín ká.”

13. Bí mo tí ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lọ́wọ́ ni Pelataya, ọmọ Bẹnaya, bá kú. Mo bá dojúbolẹ̀, mo kígbe sókè, mo ní, “Áà! OLUWA Ọlọrun, ṣé o fẹ́ pa àwọn ọmọ Israẹli yòókù tán ni?”

14. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀, ó ní:

15. “Ìwọ ọmọ eniyan, gbogbo àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu, ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn arakunrin wọn, tí ẹ jọ wà ní ìgbèkùn, àní gbogbo ilé Israẹli; wọ́n ń sọ pé, ‘Wọ́n ti lọ jìnnà kúrò lọ́dọ̀ OLUWA, OLUWA sì ti fún wa ní ilẹ̀ yìí gẹ́gẹ́ bí ohun ìní.’

16. “Nítorí náà wí fún wọn pé èmi, OLUWA Ọlọrun ní, bí mo tilẹ̀ kó wọn lọ jìnnà sí ààrin àwọn orílẹ̀-èdè, tí mo sì fọ́n wọn káàkiri ilẹ̀ ayé, sibẹsibẹ mo jẹ́ ibi mímọ́ fún wọn fún ìgbà díẹ̀ ní ilẹ̀ tí wọ́n lọ.

17. “Nítorí náà, wí fún wọn pé èmi, ‘OLUWA Ọlọrun ní n óo kó wọn jọ láti ààrin àwọn ẹ̀yà ati orílẹ̀-èdè mìíràn tí mo fọ́n wọn ká sí, n óo sì fún wọn ní ilẹ̀ Israẹli.’

18. Nígbà tí wọ́n bá dé ibẹ̀, wọn óo ṣa gbogbo ohun ẹ̀gbin ati ìríra rẹ̀ kúrò ninu rẹ̀.

19. Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;

20. kí wọ́n lè máa rìn ninu ìlànà mi, kí wọ́n sì lè máa pa òfin mi mọ́. Wọn óo jẹ́ eniyan mi, èmi náà óo sì jẹ́ Ọlọrun wọn.

21. Ṣugbọn n óo fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ jẹ àwọn tí ọkàn wọn ń fà sí àwọn ohun ẹ̀gbin ati ìríra. Èmi OLUWA Ọlọrun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”

Ka pipe ipin Isikiẹli 11