Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 10:8-19 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Ó dàbí ẹni pé àwọn Kerubu náà ní ọwọ́ bíi ti eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn.

9. Mo wòye, mo sì rí i pé àgbá mẹrin ni ó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ àwọn Kerubu náà: àgbá kọ̀ọ̀kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Kerubu kọ̀ọ̀kan. Àwọn kẹ̀kẹ́ náà ń dán yinrinyinrin bí òkúta Kirisolite.

10. Àwọn mẹrẹẹrin rí bákan náà, ó sì dàbí ìgbà tí àwọn àgbá náà wọnú ara wọn.

11. Bí wọn tí ń lọ, ibikíbi tí ó bá wu àwọn Kerubu náà ninu ẹ̀gbẹ́ mẹrẹẹrin tí wọ́n kọjú sí ni wọ́n lè lọ láì jẹ́ pé wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada, nítorí pé ibikíbi tí èyí tí ó wà níwájú bá kọjú sí ni àwọn yòókù máa ń lọ.

12. Gbogbo ara wọn àtẹ̀yìn wọn, àtọwọ́, àtìyẹ́ ati gbogbo ẹ̀gbẹ́ kẹ̀kẹ́ wọn kún fún ojú.

13. Mo gbọ́ tí wọ́n pe àwọn àgbá náà ní àgbá tí ń sáré yí.

14. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní iwájú mẹrin mẹrin. Iwájú kinni jẹ́ iwájú Kerubu, ekeji jẹ́ iwájú eniyan, ẹkẹta jẹ́ iwájú kinniun, ẹkẹrin sì jẹ́ iwájú ẹyẹ idì.

15. Àwọn Kerubu náà bá gbéra nílẹ̀, àwọn ni ẹ̀dá alààyè tí mo rí ní etí odò Kebari.

16. Bí wọn tí ń lọ, bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbá náà ń lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Bí àwọn Kerubu náà bá fẹ́ fò, tí wọ́n bá na ìyẹ́ apá wọn, àwọn àgbá náà kìí kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.

17. Bí wọn bá dúró, àwọn náà á dúró. Bí wọn bá gbéra nílẹ̀, àwọn náà á gbéra, nítorí pé ẹ̀mí àwọn ẹ̀dá alààyè náà wà ninu wọn.

18. Ìtànṣán ògo OLUWA jáde kúrò ní àbáwọlé, ó sì dúró sí orí àwọn Kerubu náà.

19. Àwọn Kerubu bá na ìyẹ́ apá wọn, wọ́n gbéra nílẹ̀ lójú mi, bí wọ́n ti ń lọ, àwọn àgbá náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Wọ́n dúró lẹ́nu ọ̀nà ilé OLUWA tí ó kọjú sí ìhà ìlà oòrùn, ìtànṣán ògo Ọlọrun Israẹli sì wà lórí wọn.

Ka pipe ipin Isikiẹli 10