Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Isikiẹli 1:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ karun-un oṣù kẹrin, ní ọgbọ̀n ọdún, èmi, Isikiẹli, ọmọ Busi, wà láàrin àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn lọ sí ilẹ̀ Babiloni. A wà lẹ́bàá odò Kebari, mo bá rí i tí ojú ọ̀run ṣí sílẹ̀; mo sì rí ìran Ọlọrun.

2. Lọ́jọ́ karun-un oṣù náà, tíí ṣe ọdún karun-un tí wọ́n ti mú ọba Jehoiakini lọ sí ìgbèkùn,

3. OLUWA bá mi sọ̀rọ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Kalidea lẹ́bàá odò Kebari; agbára OLUWA sì sọ̀kalẹ̀ sí mi lára.

4. Ninu ìran náà, mo rí i tí ìjì kan ń jà bọ̀ láti ìhà àríwá, pẹlu ìkùukùu ńlá tí ìmọ́lẹ̀ ńlá ati iná tí ń kọ mànàmànà yí ìjì náà ká, ààrin iná náà sì dàbí idẹ dídán tí ń kọ mànà.

5. Láàrin iná yìí, mo rí àwọn ẹ̀dá alààyè mẹrin kan, wọ́n dàbí eniyan.

6. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu wọn ní ojú mẹrin mẹrin ati ìyẹ́ mẹrin mẹrin.

7. Ẹsẹ̀ wọn tọ́, àtẹ́lẹsẹ̀ wọn sì dàbí pátákò mààlúù, ó ń kọ mànà bíi idẹ.

8. Wọ́n ní ọwọ́ eniyan lábẹ́ ìyẹ́ wọn mẹrẹẹrin, wọ́n ní ojú mẹ́rin ati ìyẹ́ mẹ́rin.

9. Báyìí ni ojú àwọn mẹrẹẹrin ati ìyẹ́ wọn rí: Ìyẹ́ wọn ń kan ara wọn; bí wọ́n bá ń rìn, olukuluku wọn á máa lọ siwaju tààrà, láìyà sí ibikíbi, bí wọn tí ń lọ.

10. Báyìí ni ojú wọn rí: olukuluku wọn ní ojú eniyan níwájú, àwọn mẹrẹẹrin ní ojú kinniun lápá ọ̀tún, wọ́n ní ojú akọ mààlúù lápá òsì, wọ́n sì ní ojú ẹyẹ idì lẹ́yìn.

11. Wọ́n na ìyẹ́ wọn sókè, ọ̀kọ̀ọ̀kan na ìyẹ́ meji meji kan ìyẹ́ ẹni tí ó kángun sí i, wọ́n sì fi ìyẹ́ meji meji bora.

12. Olukuluku kọjú sí ìhà mẹrin, ó sì lè lọ tààrà sí ìhà ibi tí ẹ̀mí rẹ̀ bá darí sí láì ṣẹ̀ṣẹ̀ yí ojú pada kí ó tó máa lọ.

13. Nǹkankan wà láàrin àwọn ẹ̀dá alààyè náà tí ó dàbí ẹ̀yinná tí ń jó. Ó ń lọ sókè sódò láàrin wọn bí ahọ́n iná. Iná náà mọ́lẹ̀, ó sì ń kọ mànàmànà.

Ka pipe ipin Isikiẹli 1