Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 6:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Wọn óo wí pé, “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí á pada sọ́dọ̀ OLUWA; nítorí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fà wá ya, sibẹ yóo wò wá sàn; ó ti pa wá lára lóòótọ́, ṣugbọn yóo di ọgbẹ́ wa.

2. Lẹ́yìn ọjọ́ meji, yóo sọ wá jí, ní ọjọ́ kẹta, yóo gbé wa dìde, kí á lè wà láàyè níwájú rẹ̀.

3. Ẹ jẹ́ kí á mọ̀ ọ́n, ẹ jẹ́ kí á tẹ̀síwájú kí á mọ OLUWA. Dídé rẹ̀ dájú bí àfẹ̀mọ́jú; yóo sì pada wá sọ́dọ̀ wa bí ọ̀wààrà òjò, ati bí àkọ́rọ̀ òjò tí ń bomirin ilẹ̀.”

4. Ṣugbọn OLUWA wí pé, “Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Efuraimu? Kí ni kí n ti ṣe ọ́ sí, ìwọ Juda? Ìfẹ́ yín dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí yára á gbẹ.

5. Nítorí náà ni mo fi jẹ́ kí àwọn wolii mi ké wọn lulẹ̀, mo ti fi ọ̀rọ̀ ẹnu mi pa wọ́n, ìdájọ́ mi sì yọ bí ìmọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Hosia 6