Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 5:1-6 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin alufaa! Ẹ tẹ́tí sílẹ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli ati ẹ̀yin ìdílé ọba! Ẹ̀yin ni ìdájọ́ náà dé bá; nítorí ẹ dàbí tàkúté ní Misipa, ati bí àwọ̀n tí a ta sílẹ̀ lórí òkè Tabori.

2. Wọ́n ti gbẹ́ kòtò jíjìn ní ìlú Ṣitimu; ṣugbọn n óo jẹ wọ́n níyà.

3. Mo mọ Efuraimu, bẹ́ẹ̀ ni Israẹli kò ṣàjèjì sí mi; nisinsinyii, ìwọ Efuraimu ti ṣe àgbèrè ẹ̀sìn, Israẹli sì ti di aláìmọ́.”

4. Gbogbo ibi tí wọn ń ṣe, kò jẹ́ kí wọ́n lè pada sọ́dọ̀ Ọlọrun wọn, nítorí pé ọkàn wọn kún fún ẹ̀mí àgbèrè, wọn kò sì mọ OLUWA.

5. Ìgbéraga Israẹli hàn kedere lójú rẹ̀; Efuraimu yóo kọsẹ̀, yóo sì ṣubú ninu ìwà burúkú rẹ̀, Juda náà yóo ṣubú pẹlu wọn.

6. Wọn yóo mú mààlúù ati aguntan wá, láti fi wá ojurere OLUWA, ṣugbọn wọn kò ní rí i; nítorí pé, ó ti fi ara pamọ́ fún wọn.

Ka pipe ipin Hosia 5