Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 2:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Pe arakunrin rẹ ní “Eniyan mi” kí o sì pe arabinrin rẹ ní “Ẹni tí ó rí àánú gbà.”

2. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ bá ìyá yín sọ̀rọ̀; nítorí pé kì í ṣe aya mi mọ́, ati pé èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀ mọ́. Ẹ sọ fún un pé kí ó má ṣe àgbèrè mọ́, kí ó sì fi ìṣekúṣe rẹ̀ sílẹ̀.

3. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, n óo tú u sí ìhòòhò, n óo ṣe é bí ìgbà tí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bí i. N óo ṣe é bí aṣálẹ̀, àní, bí ilẹ̀ tí ó gbẹ, n óo sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́ pa.

4. N kò ní ṣàánú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí ọmọ àgbèrè ni wọ́n.

5. Nítorí alágbèrè ni ìyá wọn, ẹni tí ó bí wọn sì ti hùwà ainitiju. Òun fúnrarẹ̀ sọ pé, “N óo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ mi, àwọn tí wọn ń fún mi ní oúnjẹ ati omi, ati aṣọ òtútù, ati aṣọ fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ funfun, ati òróró olifi ati ọtí.”

6. Nítorí náà, n óo fi ẹ̀gún ṣe ọgbà yí i ká; n óo mọ odi yí i ká, tí kò fi ní rí ọ̀nà jáde.

7. Yóo sá tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀, ṣugbọn kò ní lè bá wọn; yóo wá wọn káàkiri pẹlu ìtara, ṣugbọn kò ní rí wọn. Yóo wá wí nígbà náà pé, “N óo pada sọ́dọ̀ ọkọ mi àárọ̀, nítorí ó dára fún mi lọ́dọ̀ rẹ̀ ju ti ìsinsìnyìí lọ.”

Ka pipe ipin Hosia 2