Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 14:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọlọrun ní,“N óo gba ìwà aiṣootọ lọ́wọ́ wọn,n óo fẹ́ wọn tọkàntọkàn,nítorí n kò bínú sí wọn mọ́.

5. Bí ìrì ni n óo máa sẹ̀ sí Israẹli,ẹwà rẹ̀ yóo yọ bí òdòdó lílì,gbòǹgbò rẹ̀ yóo sì múlẹ̀ bíi gbòǹgbò igi kedari Lẹbanoni.

6. Àwọn ẹ̀ka rẹ̀ yóo tàn kálẹ̀;ẹwà rẹ̀ yóo yọ bíi ti igi olifi,òórùn rẹ̀ yóo sì dàbí ti igi Lẹbanoni.

7. Wọn óo pada sábẹ́ ààbò mi,wọn óo rúwé bí igi inú ọgbà;wọn óo sì tanná bí àjàrà,òórùn wọn óo dàbí ti waini Lẹbanoni.

8. Efuraimu yóo sọ pé, ‘kí ni mo ní ṣe pẹlu àwọn oriṣa?’Nítorí èmi ni n óo máa gbọ́ adura rẹ̀,tí n óo sì máa tọ́jú rẹ̀.Mo dàbí igi sipirẹsi tí kì í wọ́wé tòjò tẹ̀ẹ̀rùn.Lọ́dọ̀ mi ni èso rẹ̀ ti ń wá.”

9. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́n, kí ó mọ àwọn nǹkan wọnyi; kí òye rẹ̀ sì yé ẹnikẹ́ni tí ó bá lóye; nítorí pé ọ̀nà OLUWA tọ́, àwọn tí wọ́n bá dúró ṣinṣin ni yóo máa tọ̀ ọ́, ṣugbọn àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo kọsẹ̀ níbẹ̀.

Ka pipe ipin Hosia 14