Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 13:15-16 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Bí Israẹli tilẹ̀ rúwé bí ewéko etí odò, atẹ́gùn OLUWA láti ìlà oòrùn yóo fẹ́ wá, yóo wá láti inú aṣálẹ̀; orísun rẹ̀ yóo gbẹ, ojú odò rẹ̀ yóo sì gbẹ pẹlu; a óo kó ìṣúra ati ohun èlò olówó iyebíye rẹ̀ kúrò.

16. Samaria ni yóo ru ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, nítorí ó ti ṣọ̀tẹ̀ sí èmi Ọlọrun rẹ̀, ogun ni yóo pa wọ́n, a óo ṣán àwọn ọmọ wọn mọ́lẹ̀, a óo sì la inú àwọn aboyún wọn.”

Ka pipe ipin Hosia 13