Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 13:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Tẹ́lẹ̀ rí, bí ẹ̀yà Efuraimu bá sọ̀rọ̀, àwọn eniyan a máa wárìrì; wọ́n níyì láàrin àwọn ẹ̀yà Israẹli yòókù, ṣugbọn nítorí pé wọ́n bọ oriṣa Baali, wọ́n dẹ́ṣẹ̀, wọ́n sì kú.

2. Nisinsinyii, wọ́n ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, wọ́n yá ère fún ara wọn; ère fadaka, iṣẹ́ ọwọ́ eniyan, Wọ́n ń sọ pé, “Ẹ wá rúbọ sí i.” Eniyan wá ń fi ẹnu ko ère mààlúù lẹ́nu!

3. Nítorí náà, wọn óo dàbí ìkùukùu òwúrọ̀, ati bí ìrì tíí máa ń yára gbẹ, wọ́n óo dàbí ìyàngbò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kúrò ní ibi ìpakà, ati bí èéfín tí ń jáde láti ojú fèrèsé.

4. OLUWA ní, “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, láti ìgbà tí ẹ ti wà ní ilẹ̀ Ijipti: ẹ kò ní Ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì ní olùgbàlà mìíràn lẹ́yìn mi.

5. Èmi ni mo ṣe ìtọ́jú yín nígbà tí ẹ wà ninu aṣálẹ̀, ninu ilẹ̀ gbígbẹ;

6. ṣugbọn nígbà tí ẹ jẹun yó tán, ẹ̀ ń gbéraga, ẹ gbàgbé mi.

7. Nítorí náà, bíi kinniun ni n óo ṣe si yín, n óo lúgọ lẹ́bàá ọ̀nà bí àmọ̀tẹ́kùn;

Ka pipe ipin Hosia 13