Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hosia 10:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Àwọn ọmọ Israẹli dàbí àjàrà dáradára tí ń so èso pupọ. Bí èso rẹ̀ tí ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni pẹpẹ oriṣa wọn ń pọ̀ sí i. Bí àwọn ìlú wọn tí ń dára sí i ni àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn náà ń dára sí i.

2. Èké ni wọ́n, nítorí náà wọn óo jìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, OLUWA yóo wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, yóo sì fọ́ àwọn ọ̀wọ̀n oriṣa wọn.

3. Wọn óo máa wí nisinsinyii pé, “A kò ní ọba, nítorí pé a kò bẹ̀rù OLUWA; kí ni ọba kan fẹ́ ṣe fún wa?”

4. Wọ́n ń fọ́nnu lásán; wọ́n ń fi ìbúra asán dá majẹmu; nítorí náà ni ìdájọ́ ṣe dìde sí wọn bíi koríko olóró, ní poro oko.

5. Àwọn ará Samaria wárìrì fún ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù, oriṣa ìlú Betafeni. Àwọn eniyan ibẹ̀ yóo ṣọ̀fọ̀ rẹ̀, àwọn babalóòṣà rẹ̀ yóo pohùnréré ẹkún lé e lórí, nítorí ògo rẹ̀ tí ó ti fò lọ.

6. Dájúdájú, a óo gbé ère oriṣa náà lọ sí Asiria, a óo fi ṣe owó ìṣákọ́lẹ̀ fún ọba ńlá ibẹ̀. Ojú yóo ti Efuraimu, ojú yóo sì ti Israẹli nítorí ère oriṣa rẹ̀.

7. Ọba Samaria yóo parun bí ẹ̀ẹ́rún igi tí ó léfòó lórí omi.

Ka pipe ipin Hosia 10