Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Habakuku 3:4-13 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Dídán rẹ̀ dàbí ọ̀sán gangan,ìtànṣán ń ti ọwọ́ rẹ̀ jáde;níbẹ̀ ni ó fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ níwájú rẹ̀,ìyọnu sì ń tẹ̀lé e lẹ́yìn pẹ́kípẹ́kí.

6. Ó dúró, ó wọn ayé;Ó wo ayé, ó sì mi àwọn orílẹ̀-èdè tìtì;àwọn òkè ńláńlá ayérayé túká,àwọn òkè àtayébáyé sì wọlẹ̀.Ọ̀nà àtayébáyé ni ọ̀nà rẹ̀.

7. Mo rí àwọn àgọ́ Kuṣani ninu ìyọnu,àwọn aṣọ ìkélé àwọn ará ilẹ̀ Midiani sì ń mì tìtì.

8. OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni,àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí,tabi òkun ni ò ń bá bínú,nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ,tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?

9. Ìwọ tí ò ń tu àkọ̀ kúrò lára ọrun,tí o fi ọfà lé ọsán ọrun;tí o wá fi omi pín ilẹ̀ ayé.

10. Nígbà tí àwọn òkè ńlá rí ọ,wọ́n wárìrì;àgbàrá omi wọ́ kọjá;ibú òkun pariwo,ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè.

11. Oòrùn ati òṣùpá dúró ní ipò wọn,nígbà tí ọfà rẹ ń já lọ ṣòòrò,tí àwọn ọ̀kọ̀ rẹ náà ń kọ mànà,bí wọ́n ti ń fò lọ.

12. O la ayé kọjá pẹlu ibinu,o sì fi ibinu tẹ àwọn orílẹ̀-èdè mọ́lẹ̀.

13. O jáde lọ láti gba àwọn eniyan rẹ là,láti gba àwọn àyànfẹ́ rẹ là.O wó orí aṣiwaju ilẹ̀ àwọn ẹni ibi wómúwómú,o tú u sí ìhòòhò láti itan dé ọrùn.

Ka pipe ipin Habakuku 3