Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Habakuku 2:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. N óo dúró sí ibìkan lórí ilé-ìṣọ́, n óo máa wòran. N óo dúró, n óo máa retí ohun tí yóo sọ fún mi, ati irú èsì tí èmi náà óo fún un.

2. OLUWA dá mi lóhùn, ó ní: “Kọ ìran yìí sílẹ̀; kọ ọ́ sórí tabili kí ó hàn ketekete, kí ó lè rọrùn fún ẹni tí ń sáré lọ láti kà á.

3. Kọ ọ́ sílẹ̀, nítorí ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ iwájú ni; ọjọ́ náà kò ní pẹ́ dé, ohun tí o rí kì í ṣe irọ́, dájúdájú yóo ṣẹ. Bí ó bá dàbí ẹni pé ó ń pẹ́, ìwọ ṣá dúró kí o máa retí rẹ̀, dájúdájú, yóo ṣẹ, láìpẹ́.

4. Wò ó! Ẹni tí ọkàn rẹ̀ kò ṣe déédéé ninu OLUWA yóo ṣègbé; ṣugbọn olódodo yóo wà láàyè nípa igbagbọ.”

5. Ọrọ̀ a máa tan eniyan jẹ; onigbeeraga kò sì ní wà láàyè pẹ́. Ojúkòkòrò rẹ̀ dàbí isà òkú; nǹkan kì í sì í tó o, àfi bí ikú. Ó gbá gbogbo orílẹ̀-èdè jọ fún ara rẹ̀, ó sì sọ gbogbo eniyan di ti ara rẹ̀.

6. Ǹjẹ́ gbogbo àwọn eniyan wọnyi kò ní máa kẹ́gàn rẹ̀, kí wọ́n sì máa fi ṣe ẹlẹ́yà pé, “Ègbé ni fún ẹni tí ń kó ohun tí kì í ṣe tirẹ̀ jọ. Ìgbà wo ni yóo ṣe èyí dà, tí yóo máa gba ìdógò lọ́wọ́ àwọn onígbèsè rẹ̀ kiri?”

7. Ǹjẹ́ àwọn onígbèsè rẹ kò ní dìde sí ọ lójijì, kí àwọn tí wọn yóo dẹ́rùbà ọ́ sì jí dìde, kí o wá di ìkógun fún wọn?

8. Nítorí pé ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè ni o ti kó lẹ́rú, gbogbo àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù ni wọn yóo sì kó ìwọ náà lẹ́rú, nítorí ẹ̀jẹ̀ àwọn eniyan tí o ti pa, ati ìwà ipá tí o hù lórí ilẹ̀ ayé, ati èyí tí o hù sí oríṣìíríṣìí ìlú ati àwọn tí wọn ń gbé inú wọn.

9. Ẹ gbé! Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń fi ipá kó èrè burúkú jọ tí ẹ óo fi kọ́ ibùgbé sí ibi gíga, kí nǹkan burúkú kankan má baà ṣẹlẹ̀ si yín!

10. O ti kó ìtìjú bá ilé rẹ nítorí ọpọlọpọ orílẹ̀-èdè tí o parun; ìwọ náà ti wá pàdánù ẹ̀mí rẹ.

11. Nítorí òkúta yóo kígbe lára ògiri, igi ìdábùú òpó ilé yóo sì fọhùn pẹlu.

Ka pipe ipin Habakuku 2