Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 9:2-16 BIBELI MIMỌ (BM)

2. àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn.

3. Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n.

4. Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i.

5. Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn.

6. Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan.

7. Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata,

8. Porata, Adalia, Aridata,

9. Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata.

10. Àwọn mẹ́wẹ̀ẹ̀wá jẹ́ ọmọ Hamani, ọmọ Hamedata, ọ̀tá àwọn Juu, ṣugbọn wọn kò fọwọ́ kan àwọn ẹrù wọn.

11. Ní ọjọ́ náà, wọ́n mú ìròyìn iye àwọn tí wọ́n pa ní Susa wá fún ọba.

12. Ọba sọ fún Ẹsita Ayaba pé, “Àwọn Juu ti pa ẹẹdẹgbẹta (500) ọkunrin ati àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ní Susa. Kí ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè ṣe? Nisinsinyii, kí ni ìbéèrè rẹ? A óo sì ṣe é fún ọ.”

13. Ẹsita dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí á fún àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa ní àṣẹ láti ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe ní òní sí àwọn ọ̀tá wọn ní ọ̀la, kí á sì so àwọn ọmọ Hamani mẹ́wẹ̀ẹ̀wá rọ̀ sí orí igi.”

14. Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi.

15. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.

16. Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.

Ka pipe ipin Ẹsita 9