Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 9:14-24 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ọba pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Àṣẹ bá jáde láti Susa, wọ́n sì so àwọn ọmọ Hamani rọ̀ sí orí igi.

15. Ní ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa tún parapọ̀, wọ́n sì pa ọọdunrun (300) ọkunrin sí i. Ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.

16. Àwọn Juu tí wọ́n wà ní àwọn agbègbè kó ara wọn jọ láti gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn. Wọ́n pa ẹgbaa mejidinlogoji ó dín ẹgbẹrun (75,000) ninu àwọn tí wọ́n kórìíra wọn, ṣugbọn wọn kò fi ọwọ́ kan ẹrù wọn.

17. Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari ni èyí ṣẹlẹ̀. Ní ọjọ́ kẹrinla, wọ́n sinmi; ọjọ́ náà sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀.

18. Ní Susa, ọjọ́ kẹẹdogun oṣù ni wọ́n tó ṣe ayẹyẹ tiwọn. Ọjọ́ kẹtala ati ọjọ́ kẹrinla ni àwọn Juu tí wọ́n wà ní Susa pa àwọn ọ̀tá wọn, ní ọjọ́ kẹẹdogun, wọ́n sinmi, ó sì jẹ́ ọjọ́ àsè ati ayọ̀ fún wọn.

19. Ìdí nìyí tí àwọn Juu tí wọn ń gbé àwọn agbègbè fi ya ọjọ́ kẹrinla oṣù Adari sọ́tọ̀ fún ọjọ́ àsè, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn.

20. Modekai kọ gbogbo nǹkan wọnyi sílẹ̀, Ó sì fi ranṣẹ sí àwọn Juu tí wọ́n wà ní gbogbo ilẹ̀ ìjọba Ahasu-erusi ọba, ati àwọn tí wọ́n wà nítòsí ati àwọn tí wọ́n wà ní òkèèrè,

21. pé kí wọ́n ya ọjọ́ kẹrinla ati ọjọ́ kẹẹdogun oṣù Adari sọ́tọ̀,

22. gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí àwọn Juu gba ara wọn sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn, tí ìbànújẹ́ ati ẹ̀rù wọn di ayọ̀, tí ọjọ́ ọ̀fọ̀ wọn sì di ọjọ́ àjọ̀dún. Ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ọjọ́ náà ní ọjọ́ àjọ̀dún ati ayọ̀, tí wọn yóo máa gbé oúnjẹ fún ara wọn, tí wọn yóo máa fún àwọn talaka ní ẹ̀bùn.

23. Àwọn Juu gbà láti máa ṣe bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ati bí àṣẹ Modekai.

24. Nítorí Hamani, ọmọ Hamedata, láti ìran Agagi, ọ̀tá àwọn Juu ti pète láti pa àwọn Juu run. Ó ti ṣẹ́ gègé, tí wọn ń pè ní Purimu, láti mọ ọjọ́ tí yóo pa àwọn Juu run patapata.

Ka pipe ipin Ẹsita 9