Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 9:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ọjọ́ kẹtala oṣù Adari tíí ṣe oṣù kejila, nígbà tí wọ́n ń múra láti ṣe ohun tí òfin ọba wí, ní ọjọ́ tí àwọn ọ̀tá rò pé ọwọ́ wọn yóo tẹ àwọn Juu, ṣugbọn, tí ó jẹ́ ọjọ́ tí àwọn Juu ṣẹgun àwọn ọ̀tá wọn;

2. àwọn Juu péjọ ninu àwọn ìlú wọn ní àwọn ìgbèríko ilẹ̀ Ahasu-erusi ọba, wọ́n múra láti bá àwọn tí wọ́n fẹ́ pa wọ́n run jà. Kò sí ẹni tí ó lè kò wọ́n lójú nítorí pé gbogbo àwọn eniyan ni wọ́n ń bẹ̀rù wọn.

3. Gbogbo àwọn olórí àwọn agbègbè, àwọn baálẹ̀, àwọn gomina ati àwọn aláṣẹ ọba ran àwọn Juu lọ́wọ́, nítorí pé ẹ̀rù Modekai ń bà wọ́n.

4. Modekai di eniyan pataki ní ààfin; òkìkí rẹ̀ kàn dé gbogbo agbègbè, agbára rẹ̀ sì ń pọ̀ sí i.

5. Àwọn Juu fi idà pa àwọn ọ̀tá wọn, wọ́n pa wọ́n run. Ohun tí ó wù wọ́n ni wọ́n ṣe sí àwọn tí wọ́n kórìíra wọn.

6. Ní ìlú Susa nìkan, àwọn Juu pa ẹẹdẹgbẹta (500) eniyan.

7. Wọ́n sì pa Paṣandata, Dalifoni, Asipata,

8. Porata, Adalia, Aridata,

9. Pamaṣita, Arisai, Aridai ati Faisata.

Ka pipe ipin Ẹsita 9