Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 6:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ọba bèèrè pé, “Ta ló wà ninu àgbàlá?” Àkókò náà ni Hamani wọ inú àgbàlá ààfin ọba, láti bá ọba sọ̀rọ̀ láti so Modekai rọ̀ sórí igi tí ó rì mọ́lẹ̀.

5. Àwọn iranṣẹ ọba dá a lóhùn pé, “Hamani wà níbẹ̀ tí ó ń duro ní àgbàlá.” Ọba sì wí pé, “Ẹ jẹ́ kí ó wọlé.”

6. Bí Hamani tí ń wọlé ni ọba bi í pé, “Kí ló yẹ kí á ṣe fún ẹni tí inú ọba dùn sí?”Hamani rò ó ninu ara rẹ̀ pé, ta ni ọba ìbá tún dá lọ́lá bíkòṣe òun.

7. Nítorí náà, ó dá ọba lóhùn pé, “Báyìí ni ó ṣe yẹ kí á dá ẹni tí inú ọba dùn sí lọ́lá:

Ka pipe ipin Ẹsita 6