Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 6:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní òru ọjọ́ náà, ọba kò lè sùn. Ó bá pàṣẹ pé kí wọ́n gbé ìwé àkọsílẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjọba rẹ̀ wá, kí wọ́n sì kà á sí etígbọ̀ọ́ òun.

2. Wọ́n kà á ninu àkọsílẹ̀ pé Modekai tú àṣírí Bigitana ati Tereṣi, àwọn ìwẹ̀fà meji tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé ọba, tí wọ́n dìtẹ̀ láti pa Ahasu-erusi ọba.

3. Ọba bèèrè pé irú ọlá wo ni a dá Modekai fún ohun tí ó ṣe yìí? Wọ́n dá a lóhùn pé ẹnikẹ́ni kò ṣe nǹkankan fún un.

Ka pipe ipin Ẹsita 6