Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 4:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Nígbà tí Modekai gbọ́ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó fa aṣọ rẹ̀ ya. Ó fi àkísà ati eérú bo ara rẹ̀. Ó kígbe lọ sí ààrin ìlú, ó ń pohùnréré ẹkún.

2. Ó lọ sí ẹnu ọ̀nà ààfin, ṣugbọn kò wọlé nítorí ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wọ àkísà wọ inú ààfin.

3. Ní gbogbo agbègbè ati káàkiri ibi tí òfin ati àṣẹ ọba dé, ni àwọn Juu tí ń ṣọ̀fọ̀ tí wọn ń gbààwẹ̀ tẹkúntẹkún. Ọpọlọpọ wọn da aṣọ ọ̀fọ̀ bora, wọ́n sì da eérú sára.

4. Nígbà tí àwọn iranṣẹbinrin Ẹsita ati àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ sọ fún un nípa Modekai, ọkàn rẹ̀ dàrú. Ó kó aṣọ ranṣẹ sí i, kí ó lè pààrọ̀ àkísà rẹ̀, ṣugbọn Modekai kọ̀ wọ́n.

5. Ẹsita bá pe Hataki, ọ̀kan ninu àwọn ìwẹ̀fà ọba, tí ọba ti yàn láti máa ṣe iranṣẹ fún un. Ó pàṣẹ fún un pé kí ó lọ bá Modekai kí ó bèèrè ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ati ohun tí ó fà á.

6. Hataki lọ bá Modekai ní ìta gbangba, níwájú ẹnu ọ̀nà ààfin ọba.

7. Modekai sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un, títí kan iye owó tí Hamani ti pinnu láti gbé kalẹ̀ sí ilé ìṣúra ọba kí wọ́n fi pa àwọn Juu run.

8. Modekai fún Hataki ní ìwé òfin tí wọ́n ṣe ní Susa láti pa gbogbo àwọn Juu run patapata, pé kí ó fi ìwé náà han Ẹsita, kí ó sì là á yé e, kí ó lè lọ siwaju ọba láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó ṣàánú àwọn eniyan rẹ̀.

9. Hataki pada lọ ròyìn ohun tí Modekai sọ fún Ẹsita.

Ka pipe ipin Ẹsita 4