Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsita 1:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní àkókò tí Ahasu-erusi jọba ní ilẹ̀ Pasia, ìjọba rẹ̀ tàn dé agbègbè mẹtadinlaadoje (127), láti India títí dé Kuṣi ní ilẹ̀ Etiopia.

2. Nígbà tí ó wà lórí oyè ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ìjọba rẹ̀,

3. ní ọdún kẹta ìjọba rẹ̀, ó se àsè fún àwọn ìjòyè, ati àwọn olórí, àwọn òṣìṣẹ́, ati àwọn olórí ogun Pasia ati ti Media, àwọn eniyan pataki pataki tí wọ́n wà lọ́dọ̀ rẹ̀ ati àwọn gomina agbègbè rẹ̀.

4. Fún odidi ọgọsan-an (180) ọjọ́ ni ọba fi ń fi ògo ìjọba rẹ̀ hàn, pẹlu ọrọ̀ ati dúkìá rẹ̀.

5. Lẹ́yìn náà, ọba se àsè ní àgbàlá ààfin fún ọjọ́ meje, fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní Susa, àtàwọn talaka, àtàwọn eniyan ńláńlá.

6. Wọ́n ṣe ọgbà náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró ati aṣọ funfun. Wọ́n fi òwú funfun ati òwú àlàárì ṣe okùn, wọ́n fi so wọ́n mọ́ òrùka fadaka, wọ́n gbé wọn kọ́ sára òpó òkúta mabu. Wúrà ati fadaka ni wọ́n fi ṣe àwọn àga tí ó wà ninu ọgbà. Òkúta mabu pupa ati aláwọ̀ aró ni wọ́n fi ṣe gbogbo ọ̀dẹ̀dẹ̀, tí gbogbo wọn ń dán gbinringbinrin.

7. Wọ́n ń fi oríṣìíríṣìí ife wúrà mu ọtí, ọba sì pèsè ọtí lọpọlọpọ gẹ́gẹ́ bí ipò ọlá ńlá rẹ̀.

8. Àṣẹ ọba ni wọ́n tẹ̀lé nípa ọ̀rọ̀ ọtí mímu. Wọn kò fi ipá mú ẹnikẹ́ni, nítorí pé ọba ti pàṣẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ààfin pé ohun tí olukuluku bá fẹ́ ni kí wọn fi tẹ́ ẹ lọ́rùn.

9. Ayaba Faṣiti pàápàá se àsè fún àwọn obinrin ní ààfin ọba Ahasu-erusi.

10. Ní ọjọ́ keje, nígbà tí ọba mu ọtí waini tí inú rẹ̀ dùn, ó pàṣẹ fún meje ninu àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀, tí wọ́n jẹ́ iranṣẹ rẹ̀: Mehumani, Bisita ati Habona, Bigita ati Abagita, Setari ati Kakasi,

11. pé kí wọ́n lọ mú Ayaba Faṣiti wá siwaju òun, pẹlu adé lórí rẹ̀, láti fi ẹwà rẹ̀ han gbogbo àwọn eniyan ati àwọn olórí, nítorí pé ó jẹ́ arẹwà obinrin.

Ka pipe ipin Ẹsita 1