Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 8:9-18 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Ninu àwọn ọmọ Joabu, Ọbadaya, ọmọ Jehieli, ni olórí;orúkọ igba eniyan ó lé mejidinlogun (218) ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

10. Ninu àwọn ọmọ Bani, Ṣelomiti, ọmọ Josifaya, ni olórí;orúkọ ọgọjọ (160) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

11. Ninu àwọn ọmọ Bebai, Sakaraya, ọmọ Bebai, ni olórí;orúkọ eniyan mejidinlọgbọn ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

12. Ninu àwọn ọmọ Asigadi, Johanani, ọmọ Hakatani, ni olórí;orúkọ aadọfa (110) eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu rẹ̀.

13. Ninu àwọn ọmọ Adonikamu,orúkọ àwọn tí wọ́n dé lẹ́yìn àwọn tí wọ́n kọ́ dé ni:Elifeleti, Jeueli ati Ṣemaaya; orúkọ ọgọta eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.

14. Ninu àwọn ọmọ Bigifai, Utai ati Sakuri ni olórí,orúkọ aadọrin eniyan ni wọ́n kọ sílẹ̀ pẹlu wọn.

15. Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.

16. Mo bá ranṣẹ pe àwọn olórí wọn wọnyi: Elieseri, Arieli ati Ṣemaaya, Elinatani, Jaribu, Elinatani Natani, Sakaraya, ati Meṣulamu. Mo sì tún ranṣẹ pe Joiaribu ati Elinatani, tí wọ́n jẹ́ amòye.

17. Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ.

18. Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun.

Ka pipe ipin Ẹsira 8