Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 8:29-36 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.”

30. Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi gba fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò náà, wọ́n kó wọn wá sinu ilé Ọlọrun wa ní Jerusalẹmu.

31. Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà.

32. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu a wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mẹta.

33. Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui.

34. A ka gbogbo wọn, a sì ṣe àkọsílẹ̀ ohun tí ìwọ̀n ọ̀kọ̀ọ̀kan jẹ́.

35. Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun.

36. Wọ́n fún àwọn aláṣẹ ati àwọn gomina tí ọba yàn fún àwọn ìgbèríko tí wọ́n wà ní òdìkejì odò ní ìwé àṣẹ tí ọba pa; àwọn aláṣẹ náà sì ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wọn ati fún iṣẹ́ ilé Ọlọrun.

Ka pipe ipin Ẹsira 8