Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 5:4-12 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ati pé, kí ni orúkọ àwọn tí wọ́n ń kọ́ ilé yìí?”

5. Ṣugbọn Ọlọrun wà pẹlu àwọn olórí Juu, wọn kò sì lè dá wọn dúró títí tí wọn fi kọ̀wé sí Dariusi ọba, tí wọ́n sì rí èsì ìwé náà gbà.

6. Ohun tí Tatenai ati Ṣetari Bosenai ati àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn kọ sinu ìwé sí Dariusi ọba nìyí:

7. “Sí Dariusi ọba, kí ọba ó pẹ́.

8. “A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, a lọ sí agbègbè Juda, a sì dé ilé tí wọ́n kọ́ fún Ọlọrun tí ó tóbi. Òkúta ńláńlá ni wọ́n fi ń kọ́ ọ, wọ́n sì ń tẹ́ pákó sára ògiri rẹ̀. Tọkàntọkàn ni wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ náà, ó sì ń tẹ̀síwájú.

9. “A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ.

10. A bèèrè orúkọ wọn, kí á baà lè kọ orúkọ olórí wọn sílẹ̀ láti fi ranṣẹ sí kabiyesi.

11. “Ìdáhùn tí wọ́n fún wa ni pé: ‘Iranṣẹ Ọlọrun ọ̀run ati ayé ni wá. Tẹmpili tí à ń tún kọ́ yìí, ọba olókìkí kan ni ó kọ́ ọ parí ní ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn.

12. Ṣugbọn nítorí pé àwọn baba wa mú Ọlọrun ọ̀run bínú, ó fi wọ́n lé Nebukadinesari ọba Babiloni, ní ilẹ̀ Kalidea lọ́wọ́, òun ni ó wó tẹmpili yìí palẹ̀, tí ó sì kó àwọn eniyan ibẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Babilonia.

Ka pipe ipin Ẹsira 5