Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 2:53-62 BIBELI MIMỌ (BM)

53. àwọn ọmọ Bakosi, àwọn ọmọ Sisera, ati àwọn ọmọ Tema,

54. àwọn ọmọ Nesaya ati àwọn ọmọ Hatifa.

55. Àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni nìyí:àwọn ọmọ Sotai, àwọn ọmọ Hasofereti, ati àwọn ọmọ Peruda;

56. àwọn ọmọ Jaala, àwọn ọmọ Dakoni, ati àwọn ọmọ Gideli;

57. àwọn ọmọ Ṣefataya ati àwọn ọmọ Hatili, àwọn ọmọ Pokereti Hasebaimu ati àwọn ọmọ Ami.

58. Àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili ati àwọn ọmọ àwọn iranṣẹ Solomoni jẹ́ irinwo ó dín mẹjọ (392).

59. Àwọn kan wá láti Teli Mela, Teli Hariṣa, Kerubu, Adani ati Imeri tí wọn kò mọ ìdílé baba wọn tabi ìran wọn, yálà wọ́n jẹ́ ọmọ Israẹli tabi wọn kì í ṣe ọmọ Israẹli àwọn nìwọ̀nyí:

60. Àwọn ọmọ Delaaya, àwọn ọmọ Tobaya, ati àwọn ọmọ Nekoda. Gbogbo wọn jẹ́ ọtalelẹgbẹta ó dín mẹjọ (652).

61. Àwọn tí wọ́n jẹ́ ọmọ alufaa ninu wọn nìwọ̀nyí: àwọn ọmọ Habaya, àwọn ọmọ Hakosi, ati àwọn ọmọ Basilai (tí ó fẹ́ aya ninu ìdílé Basilai ará Gileadi, tí wọ́n sì ń fi orúkọ àna rẹ̀ pe àwọn ọmọ rẹ̀).

62. Wọ́n wá orúkọ wọn ninu ìwé àkọsílẹ̀ tí a kọ ní ìdílé ìdílé, ṣugbọn wọn kò rí i. Nítorí náà a kà wọ́n kún aláìmọ́, a sì yọ wọ́n kúrò ninu iṣẹ́ alufaa.

Ka pipe ipin Ẹsira 2