Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹsira 1:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Àwọn olórí ninu ìdílé ẹ̀yà Juda ati ẹ̀yà Bẹnjamini, ati àwọn alufaa, ati àwọn ọmọ Lefi sì dìde, pẹlu àwọn tí Ọlọrun ti fi sí lọ́kàn láti tún ilé OLUWA tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́.

6. Àwọn aládùúgbò wọn fi ohun èlò fadaka ati ti wúrà, ati dúkìá, ati ẹran ọ̀sìn, ati àwọn nǹkan olówó iyebíye ràn wọ́n lọ́wọ́, yàtọ̀ sí àwọn ọrẹ àtinúwá.

7. Kirusi ọba náà kó àwọn ohun èlò inú ilé OLUWA jáde, tí Nebukadinesari kó wá sinu àwọn ilé oriṣa rẹ̀, láti Jerusalẹmu.

Ka pipe ipin Ẹsira 1