Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremaya 2:11-15 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Ẹkún sísun ti sọ ojú mi di bàìbàì,ìdààmú bá ọkàn mi;ìbànújẹ́ sì mú kí ó rẹ̀wẹ̀sìnítorí ìparun àwọn eniyan mi,nítorí pé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ati àwọn ọmọ ọwọ́ ń dákú lójú pópó láàrin ìlú.

12. Bí wọ́n ti ń dákú láàrin ìlú,bí ẹni tí a ṣá lọ́gbẹ́,tí wọ́n sì ń kú lọ lẹ́yìn ìyá wọn,wọ́n ń sọkún sí àwọn ìyá wọn pé:“Ebi ń pa wá, òùngbẹ sì ń gbẹ wá.”

13. Kí ni mo lè sọ nípa rẹ,kí sì ni ǹ bá fi ọ́ wé, Jerusalẹmu?Kí ni mo lè fi wé ọ,kí n lè tù ọ́ ninu, ìwọ Sioni?Nítorí bí omi òkun ni ìparun rẹ gbòòrò;ta ló lè mú ọ pada bọ̀ sípò?

14. Ìran èké ati ti ẹ̀tàn ni àwọn wolii rẹ ń rí sí ọ;wọn kò fi ẹ̀ṣẹ̀ rẹ hàn ọ́,kí wọ́n lè dá ire rẹ pada,ṣugbọn wọ́n ń ríran èké ati ìran ẹ̀tàn sí ọ.

15. Gbogbo àwọn tí ń rékọjá lọń pàtẹ́wọ́ lé ọ lórí,wọ́n ń pòṣé,wọ́n sì ń mi orí wọn sí ọ, Jerusalẹmu.Wọ́n ń sọ pé:“Ṣé ìlú yìí ni à ń pè níìlú tí ó lẹ́wà jùlọ,tí ó jẹ́ ayọ̀ gbogbo ayé?”

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremaya 2