Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 34:31-35 BIBELI MIMỌ (BM)

31. Ṣugbọn Mose pè wọ́n, Aaroni ati gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sì bá wọn sọ̀rọ̀.

32. Lẹ́yìn náà, gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì ṣe gbogbo ohun tí Ọlọrun bá a sọ lórí òkè Sinai lófin fún wọn.

33. Lẹ́yìn tí Mose bá wọn sọ̀rọ̀ tán ó fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀.

34. Ṣugbọn nígbà tí Mose bá wọlé lọ, láti bá OLUWA sọ̀rọ̀, a máa mú aṣọ ìbòjú náà kúrò ní ojú títí yóo fi jáde, nígbà tí ó bá sì jáde, yóo sọ ohun tí OLUWA bá pa láṣẹ fún àwọn ọmọ Israẹli.

35. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe akiyesi ojú Mose, pé ó ń kọ mànàmànà; Mose a sì máa fi aṣọ ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí yóo fi di ìgbà tí yóo tún wọ ilé lọ láti bá OLUWA sọ̀rọ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 34