Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 32:15-25 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mose bá yipada, ó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè, tòun ti wàláà òkúta ẹ̀rí mejeeji lọ́wọ́ rẹ̀, àwọn wàláà òkúta tí Ọlọrun ti kọ nǹkan sí lójú mejeeji.

16. Iṣẹ́ ọwọ́ Ọlọrun ni àwọn wàláà òkúta náà, Ọlọrun tìkararẹ̀ ni ó sì fi ọwọ́ ara rẹ̀ kọ ohun tí ó wà lára wọn.

17. Bí Joṣua ti gbọ́ ariwo àwọn eniyan náà tí wọn ń ké, ó wí fún Mose pé, “Ariwo ogun wà ninu àgọ́.”

18. Ṣugbọn Mose dáhùn pé, “Èyí kì í ṣe ìhó ìṣẹ́gun, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe igbe ẹni tí wọ́n ṣẹgun rẹ̀, ìró orin ni èyí tí mò ń gbọ́ yìí.”

19. Bí ó ti súnmọ́ tòsí àgọ́, bẹ́ẹ̀ ni ó rí ère ọmọ mààlúù, ó sì rí àwọn eniyan tí wọn ń jó. Inú bí Mose gidigidi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ju àwọn wàláà òkúta náà mọ́lẹ̀, ó sì fọ́ wọn ní ẹsẹ̀ òkè náà.

20. Ó mú ère ọmọ mààlúù náà, tí wọ́n fi wúrà ṣe, ó sun ún níná, ó lọ̀ ọ́ lúbúlúbú, ó kù ú sójú omi, ó sì gbé e fún àwọn ọmọ Israẹli mu.

21. Mose bi Aaroni pé, “Kí ni àwọn eniyan wọnyi fi ṣe ọ́, tí o fi mú ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá yìí wá sórí wọn?”

22. Aaroni bá dáhùn, ó ní, “Má bínú, oluwa mi, ṣebí ìwọ náà mọ àwọn eniyan wọnyi pé eeyankeeyan ni wọ́n,

23. àwọn ni wọ́n wá bá mi tí wọ́n ní, ‘Ṣe oriṣa fún wa tí yóo máa ṣáájú wa lọ, nítorí pé a kò mọ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí Mose, tí ó kó wa wá láti ilẹ̀ Ijipti.’

24. Ni mo bá wí fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó bá ní wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Wọ́n kó wọn fún mi, ni mo bá dà wọ́n sinu iná, òun ni mo sì fi yá ère mààlúù yìí.”

25. Nígbà tí Mose rí i pé Aaroni ti dá rúdurùdu sílẹ̀, láàrin àwọn eniyan náà, ati pé apá kò ká wọn mọ́, ọ̀rọ̀ náà sì sọ wọ́n di ẹni ìtìjú níwájú àwọn ọ̀tá wọn,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 32