Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 30:32-37 BIBELI MIMỌ (BM)

32. ẹ kò gbọdọ̀ dà á sí ara àwọn eniyan lásán, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe òróró mìíràn tí ó dàbí rẹ̀. Mímọ́ ni, ẹ sì gbọdọ̀ kà á sí mímọ́.

33. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe irú rẹ̀, tabi ẹnikẹ́ni tí ó bá dà á sórí ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe alufaa, a óo yọ olúwarẹ̀ kúrò lára àwọn eniyan rẹ̀.’ ”

34. OLUWA wí fún Mose pé, “Mú àwọn ohun ìkunra olóòórùn dídùn wọnyi: sitakite, ati onika, ati galibanumi ati ojúlówó turari olóòórùn dídùn, gbogbo wọn gbọdọ̀ jẹ́ ìwọ̀n kan náà.

35. Lọ̀ wọ́n pọ̀ gẹ́gẹ́ bíi ti àwọn tí wọn ń ṣe turari, kí o fi iyọ̀ sí i; yóo sì jẹ́ mímọ́.

36. Bù ninu rẹ̀, kí o gún un lúbúlúbú. Lẹ́yìn náà, bù díẹ̀ ninu lúbúlúbú yìí, kí o fi siwaju àpótí ẹ̀rí ninu àgọ́ àjọ, níbi tí n óo ti bá ọ pàdé, yóo jẹ́ mímọ́ fún yín.

37. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe irú turari náà fún ara yín, ṣugbọn ẹ mú un gẹ́gẹ́ bí ohun mímọ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún OLUWA.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 30