Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 28:19-35 BIBELI MIMỌ (BM)

19. Kí ẹsẹ̀ kẹta jẹ́ òkúta jasiniti, ati òkúta agate, ati òkúta ametisti.

20. Kí ẹsẹ̀ kẹrin jẹ́ òkúta bẹrili, ati òkúta onikisi, ati òkúta jasiperi, wúrà ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òkúta wọnyi.

21. Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.

22. Fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà.

23. Kí o da òrùka wúrà meji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.

24. Fi ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji bọ inú òrùka mejeeji yìí.

25. So etí kinni keji àwọn ẹ̀wọ̀n mejeeji mọ́ ojú ìdè mejeeji, kí o so ó mọ́ èjìká efodu náà níwájú.

26. Da òrùka wúrà meji, sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà lọ́wọ́ inú, ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

27. Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

28. Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ aró ni wọn yóo máa fi bọ inú àwọn òrùka ara efodu ati àwọn òrùka ara ìgbàyà, láti dè wọ́n pọ̀ kí ó lè máa wà lórí àmùrè tí ó wà lára efodu náà, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu.

29. “Orúkọ àwọn ọmọ Israẹli yóo máa wà lára Aaroni, lórí ìgbàyà ìdájọ́, ní oókan àyà rẹ̀, nígbà tí ó bá wọ ibi mímọ́ lọ, fún ìrántí nígbà gbogbo níwájú OLUWA.

30. Fi òkúta Urimu ati òkúta Tumimu sí ara ìgbàyà ìdájọ́, kí wọn kí ó sì máa wà ní oókan àyà Aaroni, nígbà tí ó bá lọ siwaju OLUWA. Bẹ́ẹ̀ ni Aaroni yóo ṣe máa ru ìdájọ́ àwọn ọmọ Israẹli sí oókan àyà rẹ̀, nígbà gbogbo níwájú OLUWA.

31. “O óo fi aṣọ aláwọ̀ aró rán ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ sí efodu náà.

32. Yọ ọrùn sí ẹ̀wù náà, kí o sì fi aṣọ bí ọ̀já tẹ́ẹ́rẹ́ gbá a lọ́rùn yípo, bí wọ́n ti máa ń fi aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ gbá ọrùn ẹ̀wù, kí ó má baà ya.

33. Fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ya àwòrán èso pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀, sì fi agogo ojúlówó wúrà kéékèèké kọ̀ọ̀kan la àwọn àwòrán èso pomegiranate náà láàrin, yípo etí àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà, nísàlẹ̀.

34. Agogo wúrà kan, àwòrán èso pomegiranate kan, bẹ́ẹ̀ ni kí o tò wọ́n sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ efodu náà.

35. Èyí ni Aaroni yóo máa wọ̀ nígbà tí ó bá ń ṣe iṣẹ́ alufaa rẹ̀, yóo sì máa gbọ́ ìró rẹ̀ nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ lọ níwájú OLUWA ati ìgbà tí ó bá ń jáde, kí ó má baà kú.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 28