Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 28:13-28 BIBELI MIMỌ (BM)

13. O óo ṣe àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà,

14. ati ẹ̀wọ̀n wúrà meji tí a lọ́ pọ̀ bí okùn, kí o sì so àwọn ẹ̀wọ̀n wúrà náà mọ́ àwọn ìtẹ́lẹ̀ wúrà náà.

15. “Ṣe ìgbàyà ìdájọ́, èyí tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà dáradára sí lára, gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọnà ara efodu náà: wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, aláwọ̀ elése àlùkò, aláwọ̀ pupa ati aṣọ ọ̀gbọ̀ tí ó ní ìlà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ni kí o fi ṣe é.

16. Bákan náà ni ìbú ati òòró rẹ̀ yóo rí, ìṣẹ́po meji ni yóo jẹ́, ìbú ati òòró rẹ̀ yóo sì jẹ́ ìká kọ̀ọ̀kan.

17. To òkúta olówó iyebíye sí ara rẹ̀ ní ẹsẹ̀ mẹrin, kí ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ jẹ́ òkúta sadiu, ati òkúta topasi, ati òkúta kabọnku.

18. Kí ẹsẹ̀ keji jẹ́ òkúta emeradi, ati òkúta safire, ati òkúta dayamọndi.

19. Kí ẹsẹ̀ kẹta jẹ́ òkúta jasiniti, ati òkúta agate, ati òkúta ametisti.

20. Kí ẹsẹ̀ kẹrin jẹ́ òkúta bẹrili, ati òkúta onikisi, ati òkúta jasiperi, wúrà ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ àwọn òkúta wọnyi.

21. Oríṣìí òkúta mejila ni yóo wà, orúkọ wọn yóo dàbí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli; wọn yóo dàbí èdìdì, wọn yóo sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejila sí ara àwọn òkúta mejeejila, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.

22. Fi ojúlówó wúrà ṣe ẹ̀wọ̀n tí a lọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí okùn fún ìgbàyà náà.

23. Kí o da òrùka wúrà meji sí etí kinni keji ìgbàyà náà.

24. Fi ẹ̀wọ̀n wúrà mejeeji bọ inú òrùka mejeeji yìí.

25. So etí kinni keji àwọn ẹ̀wọ̀n mejeeji mọ́ ojú ìdè mejeeji, kí o so ó mọ́ èjìká efodu náà níwájú.

26. Da òrùka wúrà meji, sì dè wọ́n mọ́ etí kinni keji ìgbàyà náà lọ́wọ́ inú, ní ẹ̀gbẹ́ tí ó kan ara efodu.

27. Lẹ́yìn náà, da òrùka wúrà meji mìíràn, kí o dè wọ́n mọ́ ìsàlẹ̀ àwọn èjìká efodu, níwájú ibi tí ó ti so pọ̀ mọ́ àmùrè rẹ̀.

28. Aṣọ tẹ́ẹ́rẹ́ aláwọ̀ aró ni wọn yóo máa fi bọ inú àwọn òrùka ara efodu ati àwọn òrùka ara ìgbàyà, láti dè wọ́n pọ̀ kí ó lè máa wà lórí àmùrè tí ó wà lára efodu náà, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 28