Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 27:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. “Ṣe àgbàlá kan sinu àgọ́ náà. Aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa apá gúsù àgbàlá náà, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ,

10. àwọn òpó rẹ̀ yóo jẹ́ ogún, ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ yóo sì jẹ́ ogún bákan náà, idẹ ni o óo fi ṣe wọ́n, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe àwọn ìkọ́ ati òpó rẹ̀.

11. Bákan náà, aṣọ tí o óo ta sí ẹ̀gbẹ́ àríwá àgbàlá náà yóo gùn ní ọgọrun-un igbọnwọ, àwọn òpó ti ẹ̀gbẹ́ náà yóo jẹ́ ogún bákan náà, pẹlu ogún ìtẹ́lẹ̀ tí a fi idẹ ṣe, ṣugbọn fadaka ni kí o fi ṣe ìkọ́ ati òpó wọn.

12. Aṣọ títa yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ̀ oòrùn àgbàlá náà, gígùn rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, yóo ní òpó mẹ́wàá, òpó kọ̀ọ̀kan yóo ní ìtẹ́lẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

13. Fífẹ̀ àgbàlá náà, láti iwájú títí dé ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ.

14. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta.

15. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ẹnu ọ̀nà náà, òun náà yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo sì ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta bákan náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 27