Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 27:13-18 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Fífẹ̀ àgbàlá náà, láti iwájú títí dé ẹ̀gbẹ́ ìlà oòrùn, yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ.

14. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà, yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta.

15. Aṣọ títa kan yóo wà ní ẹ̀gbẹ́ keji ẹnu ọ̀nà náà, òun náà yóo gùn ní igbọnwọ mẹẹdogun, yóo sì ní òpó mẹta ati ìtẹ́lẹ̀ mẹta bákan náà.

16. Ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà yóo ní aṣọ títa kan tí yóo gùn ní ogún igbọnwọ, aṣọ aláwọ̀ aró, èyí tí ó ní àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa fòò ati aṣọ ọ̀gbọ̀ ni kí o fi ṣe aṣọ títa náà, kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí etí rẹ̀, kí ó ní òpó mẹrin ati ìtẹ́lẹ̀ mẹrin.

17. Fadaka ni kí o fi bo gbogbo òpó inú àgọ́ náà, fadaka náà ni kí o sì fi ṣe gbogbo ìkọ́ àwọn òpó náà, àfi àwọn ìtẹ́lẹ̀ rẹ̀ ni kí o fi idẹ ṣe.

18. Gígùn àgbàlá náà yóo jẹ́ ọgọrun-un igbọnwọ, ìbú rẹ̀ yóo jẹ́ aadọta igbọnwọ, gíga rẹ̀ yóo sì jẹ́ igbọnwọ marun-un pẹlu aṣọ títa tí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ ṣe ati ìtẹ́lẹ̀ idẹ.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 27