Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 26:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. “Aṣọ títa mẹ́wàá ni kí o fi ṣe inú àgọ́ mi, kí aṣọ náà jẹ́ aṣọ ọ̀gbọ̀ funfun, kí wọ́n dárà sí aṣọ náà pẹlu àwọ̀ aró, ati àwọ̀ elése àlùkò ati àwọ̀ pupa, kí àwọn tí wọ́n bá mọ iṣẹ́ ọnà ya àwòrán Kerubu sí ara gbogbo aṣọ títa náà.

2. Kí gígùn aṣọ títa kọ̀ọ̀kan jẹ́ igbọnwọ mejidinlọgbọn, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ títa náà gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.

3. Rán marun-un ninu àwọn aṣọ títa náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán marun-un yòókù pọ̀.

4. Fi aṣọ aláwọ̀ aró ṣe ojóbó sí etí ẹ̀gbẹ́ tí ó wà ní òde ninu aṣọ àránpọ̀ kọ̀ọ̀kan.

5. Aadọta ojóbó ni kí o ṣe sí àránpọ̀ aṣọ kinni, lẹ́yìn náà ṣe aadọta ojóbó sí àránpọ̀ aṣọ keji, kí àwọn ojóbó náà lè kọ ojú sí ara wọn.

6. Lẹ́yìn náà, ṣe aadọta ìkọ́ wúrà, kí o fi kọ́ àwọn ojóbó àránpọ̀ aṣọ mejeeji, kí àgọ́ náà lè dúró ní odidi kan ṣoṣo.

7. “Fi awẹ́ aṣọ mọkanla tí wọ́n fi irun ewúrẹ́ ṣe, ṣe ìbòrí kan fún àgọ́ náà.

8. Kí gígùn ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu aṣọ náà jẹ́ ọgbọ̀n igbọnwọ, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ igbọnwọ mẹrin, kí àwọn aṣọ mọkọọkanla gùn bákan náà, kí wọ́n sì fẹ̀ bákan náà.

9. Rán marun-un ninu àwọn aṣọ náà pọ̀, lẹ́yìn náà, rán mẹfa yòókù pọ̀, kí o ṣẹ́ aṣọ kẹfa po bo iwájú àgọ́ náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 26