Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 25:28-38 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.

29. Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù.

30. Gbé tabili náà kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, kí burẹdi ìfihàn sì máa wà ní orí rẹ̀ nígbà gbogbo.

31. “Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan.

32. Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji.

33. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi.

34. Kí òdòdó aláràbarà mẹrin wà lórí ọ̀pá fìtílà náà gan-an, kí àwọn òdòdó náà dàbí alimọndi tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ so,

35. kí àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kéékèèké kọ̀ọ̀kan wà lábẹ́ ẹ̀ka meji meji tí ó ya lára ọ̀pá fìtílà náà.

36. Àṣepọ̀ ni kí wọ́n ṣe ọ̀pá fìtílà, ati àwọn ẹ̀ka rẹ̀, ati àṣẹ̀ṣẹ̀yọ èso kékeré abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀. Ojúlówó wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n sì fi ṣe gbogbo rẹ̀.

37. Ṣe fìtílà meje fún ọ̀pá fìtílà náà, kí o sì gbé wọn ka orí ọ̀pá náà ní ọ̀nà tí gbogbo wọn yóo fi kọjú siwaju.

38. Ojúlówó wúrà ni kí o fi ṣe ẹnu rẹ̀ ati àwo pẹrẹsẹ rẹ̀,

Ka pipe ipin Ẹkisodu 25