Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 25:17-33 BIBELI MIMỌ (BM)

17. “Lẹ́yìn náà, fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

18. Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà.

19. Àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn Kerubu náà, kí ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀, kí ekeji sì wà ní òkè rẹ̀.

20. Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà.

21. Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀.

22. Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.

23. “Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

24. Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo.

25. Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo.

26. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

27. Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

28. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.

29. Fi ojúlówó wúrà ṣe àwọn àwo ati àwo kòtò fún turari ati ìgò ati abọ́ tí wọn yóo fi máa ta ohun mímu sílẹ̀ fún ètùtù.

30. Gbé tabili náà kalẹ̀ níwájú àpótí ẹ̀rí, kí burẹdi ìfihàn sì máa wà ní orí rẹ̀ nígbà gbogbo.

31. “Fi ojúlówó wúrà ṣe ọ̀pá fìtílà kan. Wúrà tí wọ́n fi òòlù lù ni kí wọ́n fi ṣe ìtẹ́lẹ̀ ati ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe é ní àṣepọ̀ mọ́ òkè ọ̀pá fìtílà náà; kí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà bí òdòdó tí wọn yóo fi dárà sí ìdí fìtílà kọ̀ọ̀kan.

32. Ṣe ẹ̀ka mẹfa sára ọ̀pá fìtílà náà, mẹta ní ẹ̀gbẹ́ kinni, ati mẹta ní ẹ̀gbẹ́ keji.

33. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀ka mẹfẹẹfa yìí ní iṣẹ́ ọnà bí òdòdó aláràbarà mẹta mẹta tí ó dàbí òdòdó alimọndi.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 25