Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 25:10-28 BIBELI MIMỌ (BM)

10. “Kí wọ́n fi igi akasia kan àpótí kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó fẹ̀ ní igbọnwọ kan ààbọ̀, kí ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀.

11. Fi ojúlówó wúrà bò ó ninu ati lóde, kí o sì fi wúrà gbá a létí yípo.

12. Fi wúrà ṣe òrùka mẹrin, kí o jó wọn mọ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹrẹẹrin; meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni, meji lẹ́gbẹ̀ẹ́ keji.

13. Fi igi akasia ṣe àwọn ọ̀pá, kí o sì fi wúrà bò wọ́n.

14. Kí o ti àwọn ọ̀pá náà bọ àwọn òrùka tí wọ́n wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kinni keji àpótí náà láti máa fi gbé e.

15. Kí àwọn ọ̀pá yìí máa wà ninu àwọn òrùka tí ó wá lẹ́gbẹ̀ẹ́ àpótí yìí nígbà gbogbo, kí ẹnikẹ́ni má ṣe fà wọ́n yọ.

16. Kí o fi àkọsílẹ̀ majẹmu ẹ̀rí tí n óo gbé lé ọ lọ́wọ́ sinu àpótí náà.

17. “Lẹ́yìn náà, fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó sì fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

18. Fi wúrà tí wọ́n fi ọmọ owú lù ṣe Kerubu meji, kí ọ̀kọ̀ọ̀kan wà ní ẹ̀gbẹ́ kinni keji ìtẹ́ àánú náà.

19. Àṣepọ̀ mọ́ ìtẹ́ àánú ni kí o ṣe àwọn Kerubu náà, kí ọ̀kan wà ní ìsàlẹ̀, kí ekeji sì wà ní òkè rẹ̀.

20. Kí àwọn Kerubu náà na ìyẹ́ wọn bo ìtẹ́ àánú, kí wọ́n kọjú sí ara wọn, kí àwọn mejeeji sì máa wo ìtẹ́ àánú náà.

21. Gbé ìtẹ́ àánú náà ka orí àpótí náà, kí o sì fi ẹ̀rí majẹmu tí n óo fún ọ sinu rẹ̀.

22. Níbẹ̀ ni n óo ti máa pàdé rẹ; láti òkè ìtẹ́ àánú, ní ààrin àwọn Kerubu mejeeji tí wọ́n wà lórí àpótí ẹ̀rí ni n óo ti máa bá ọ sọ nípa gbogbo òfin tí mo bá fẹ́ fún àwọn eniyan Israẹli.

23. “Fi igi akasia kan tabili kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji, kí ó fẹ̀ ní ìwọ̀n igbọnwọ kan, kí ó sì ga ní ìwọ̀n igbọnwọ kan ààbọ̀.

24. Yọ́ ojúlówó wúrà bò ó, kí o sì yọ́ ojúlówó wúrà sí gbogbo etí rẹ̀ yípo.

25. Lẹ́yìn náà, ṣe ìgbátí kan yíká etí tabili náà, kí ó fẹ̀ ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ kan, kí o sì yọ́ wúrà bo ìgbátí náà yípo.

26. Lẹ́yìn náà, ṣe òrùka wúrà mẹrin, kí o sì jó òrùka kọ̀ọ̀kan mọ́ ibi ẹsẹ̀ kọ̀ọ̀kan.

27. Kí òrùka kọ̀ọ̀kan súnmọ́ ìgbátí tabili náà, òrùka wọnyi ni wọn yóo máa ti ọ̀pá bọ̀ láti fi gbé tabili náà.

28. Fi igi akasia ṣe ọ̀pá, kí o sì yọ́ wúrà bò wọ́n; àwọn ọ̀pá wọnyi ni wọn yóo máa fi gbé tabili náà.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 25