Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 25:1-10 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA rán Mose ó ní,

2. “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé kí wọ́n gba ọrẹ jọ fún mi, ọwọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá ti ọkàn rẹ̀ wá láti ṣe ọrẹ àtinúwá ni kí wọ́n ti gba ọrẹ náà.

3. Àwọn nǹkan ọrẹ tí wọn yóo gbà lọ́wọ́ wọn ni: wúrà, fadaka, idẹ;

4. aṣọ aláró, aṣọ elése àlùkò, aṣọ pupa, aṣọ funfun, ati irun ewúrẹ́;

5. awọ àgbò tí wọ́n ṣe, tí ó jẹ́ pupa, ati ti ewúrẹ́, igi akasia;

6. òróró fún àwọn fìtílà, ati àwọn èròjà olóòórùn dídùn fún òróró tí wọn ń ta sí eniyan lórí, ati turari,

7. òkúta onikisi ati àwọn òkúta tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ọnà sára efodu tí àwọn alufaa ń wọ̀, ati ohun tí wọn ń dà bo àyà;

8. kí wọ́n sì ṣe ibùgbé fún mi, kí n lè máa gbé ààrin wọn.

9. Bí mo ti júwe fún ọ gan-an ni kí o ṣe àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀.

10. “Kí wọ́n fi igi akasia kan àpótí kan, kí ó gùn ní ìwọ̀n igbọnwọ meji ààbọ̀, kí ó fẹ̀ ní igbọnwọ kan ààbọ̀, kí ó sì ga ní igbọnwọ kan ààbọ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 25