Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 23:22-31 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Ṣugbọn bí o bá gbọ́ tirẹ̀, tí o sì ṣe bí mo ti wí, nígbà náà ni n óo gbógun ti àwọn tí ó bá gbógun tì ọ́, n óo sì dojú ìjà kọ àwọn ọ̀tá rẹ.

23. Nígbà tí angẹli mi bá ń lọ níwájú rẹ, tí ó bá mú ọ dé ilẹ̀ àwọn ará Amori, ati ti àwọn ará Hiti, ati ti àwọn ará Perisi, ati ti àwọn ará Kenaani, ati ti àwọn ará Hifi, ati ti àwọn ará Jebusi, tí mo bá sì pa wọ́n run,

24. o kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún àwọn oriṣa wọn, o kò sì gbọdọ̀ bọ wọ́n, tabi kí o hu irú ìwà ìbọ̀rìṣà tí àwọn ará ibẹ̀ ń hù. Wíwó ni kí o wó àwọn ilé oriṣa wọn lulẹ̀, kí o sì fọ́ gbogbo àwọn òpó wọn túútúú.

25. Èmi OLUWA Ọlọrun yín ni kí ẹ máa sìn. N óo pèsè ọpọlọpọ nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu fún yín, n óo sì mú àìsàn kúrò láàrin yín.

26. Ẹyọ oyún kan kò ní bàjẹ́ lára àwọn obinrin yín, bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ obinrin kan kò ní yàgàn ninu gbogbo ilẹ̀ yín. N óo jẹ́ kí ẹ gbó, kí ẹ sì tọ́.

27. “N óo da jìnnìjìnnì bo gbogbo àwọn tí ẹ̀ ń lọ dojú ìjà kọ, rúdurùdu yóo sì bẹ́ sí ààrin wọn, gbogbo àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa sálọ, nígbàkúùgbà tí wọ́n bá gbúròó yín.

28. N óo rán àwọn agbọ́n ńlá ṣáájú yín, tí yóo lé àwọn ará Hifi ati àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti jáde fún yín.

29. N kò ní tíì lé wọn jáde fún ọdún kan, kí ilẹ̀ náà má baà di aṣálẹ̀, kí àwọn ẹranko sì pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí wọn yóo gba gbogbo ilẹ̀ náà mọ́ yín lọ́wọ́.

30. Díẹ̀díẹ̀ ni n óo máa lé wọn jáde fún yín, títí tí ẹ óo fi di pupọ tí ẹ óo sì gba gbogbo ilẹ̀ náà.

31. Ilẹ̀ yín yóo lọ títí kan Òkun Pupa, ati títí lọ kan òkun àwọn ará Filistia, láti aṣálẹ̀ títí lọ kan odò Yufurate, nítorí pé n óo fi àwọn tí wọn ń gbé ilẹ̀ náà le yín lọ́wọ́, ẹ óo sì lé wọn jáde.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 23