Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 20:18-26 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Nígbà tí àwọn eniyan náà gbọ́ bí ààrá ti ń sán, tí wọ́n rí i bí mànàmáná ti ń kọ, tí wọ́n gbọ́ dídún ìró fèrè, tí wọ́n rí i tí òkè ń rú èéfín, ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì wárìrì. Wọ́n dúró lókèèrè,

19. wọ́n sì wí fún Mose pé, “Ìwọ ni kí o máa bá wa sọ̀rọ̀, a óo máa gbọ́; má jẹ́ kí Ọlọrun bá wa sọ̀rọ̀ mọ́, kí a má baà kú.”

20. Mose bá dá àwọn eniyan náà lóhùn pé, “Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù bà yín, Ọlọrun wá dán yín wò ni, kí ẹ lè máa bẹ̀rù rẹ̀, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀.”

21. Àwọn eniyan náà dúró lókèèrè, bí Mose tí ń súnmọ́ òkùnkùn biribiri tí ó ṣú bo ibi tí Ọlọrun wà.

22. OLUWA ní kí Mose sọ fún àwọn eniyan Israẹli pé, “Ẹ ti rí i fúnra yín pé mo ba yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá.

23. Ẹ kò gbọdọ̀ fi wúrà tabi fadaka yá ère láti máa bọ, àfi èmi nìkan ni kí ẹ máa sìn.

24. Yẹ̀ẹ̀pẹ̀ ni kí ẹ fi tẹ́ pẹpẹ fún mi, kí ẹ sì máa rú ẹbọ sísun yín ati ẹbọ alaafia yín lórí rẹ̀, kì báà ṣe aguntan tabi mààlúù. Níbikíbi tí mo bá pa láṣẹ pé kí ẹ ti sìn mí, n óo tọ̀ yín wá, n óo sì súre fún yín níbẹ̀.

25. Bí ẹ bá fi òkúta tẹ́ pẹpẹ fún mi, ẹ má lo òkúta tí wọ́n bá gbẹ́, nítorí pé bí ẹ bá fi ohun èlò yín ṣiṣẹ́ lára òkúta náà, ẹ ti sọ ọ́ di aláìmọ́.

26. Ẹ kò gbọdọ̀ tẹ́ pẹpẹ tí ẹ óo máa fi àtẹ̀gùn gùn, kí wọ́n má baà máa rí ìhòòhò yín lórí rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 20