Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 20:1-9 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọlọrun sì sọ ọ̀rọ̀ wọnyii, ó ní,

2. “Èmi ni OLUWA Ọlọrun yín, tí ó mu yín jáde láti ilẹ̀ Ijipti, ní oko ẹrú tí ẹ wà:

3. “O kò gbọdọ̀ ní ọlọrun mìíràn lẹ́yìn mi.

4. “O kò gbọdọ̀ yá èrekére fún ara rẹ, kì báà ṣe àwòrán ohun tí ó wà ní òkè ọ̀run, tabi ti ohun tí ó wà ní orí ilẹ̀, tabi ti ohun tí ó wà ninu omi ní abẹ́ ilẹ̀.

5. O kò gbọdọ̀ foríbalẹ̀ fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni o kò gbọdọ̀ bọ wọ́n; nítorí Ọlọrun tí í máa ń jowú ni èmi OLUWA Ọlọrun rẹ. Èmi a máa fi ẹ̀ṣẹ̀ baba bi ọmọ, títí dé ìran kẹta ati ẹkẹrin lára àwọn tí wọ́n kórìíra mi.

6. Ṣugbọn èmi a máa fi ìfẹ́ mi tí kì í yẹ̀ hàn sí ẹgbẹẹgbẹrun àwọn tí wọ́n fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

7. “O kò gbọdọ̀ pe orúkọ OLUWA Ọlọrun rẹ lásán, nítorí pé, èmi OLUWA yóo dá ẹnikẹ́ni tí ó bá pe orúkọ mi lásán lẹ́bi.

8. “Ranti ọjọ́ ìsinmi kí o sì yà á sí mímọ́.

9. Ọjọ́ mẹfa ni kí olukuluku máa fi ṣiṣẹ́, kí ó sì máa fi parí ohun tí ó bá níláti ṣe.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 20