Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 18:15-27 BIBELI MIMỌ (BM)

15. Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe.

16. Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.”

17. Baba iyawo rẹ̀ bá bá a wí pé, “Ohun tí ò ń ṣe yìí kò dára.

18. Àtìwọ àtàwọn eniyan tí wọ́n wà pẹlu rẹ, ẹ óo pa ara yín; ohun tí ò ń ṣe yìí ti pọ̀ jù fún ọ, o kò lè dá a ṣe.

19. Gbọ́ ohun tí n óo sọ fún ọ yìí, ìmọ̀ràn ni mo fẹ́ gbà ọ́, Ọlọrun yóo sì wà pẹlu rẹ. Ó dára kí o máa ṣe aṣojú àwọn eniyan náà níwájú Ọlọrun, kí o sì máa bá wọn kó ẹ̀dùn ọkàn wọn tọ Ọlọrun lọ;

20. ó sì dára bákan náà pẹlu kí o máa kọ́ wọn ní òfin ati ìlànà, kí o sì máa fi ọ̀nà tí wọn yóo tọ̀ hàn wọ́n, ati ohun tí wọ́n gbọdọ̀ máa ṣe.

21. Ohun tí ó yẹ kí o ṣe nìyí, yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè jẹ́ alákòóso, àwọn tí wọ́n bẹ̀rù Ọlọrun, tí wọ́n ṣe é gbẹ́kẹ̀lé, tí wọ́n sì kórìíra àbẹ̀tẹ́lẹ̀; fi wọ́n ṣe alákòóso àwọn eniyan wọnyi, fi àwọn kan ṣe alákòóso lórí ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn kan lórí ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn kan lórí araadọta, ati àwọn mìíràn lórí eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.

22. Jẹ́ kí wọn máa ṣe onídàájọ́ fún àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá jẹ́ pataki pataki nìkan ni wọn yóo máa kó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ, kí wọ́n máa parí àwọn ẹjọ́ kéékèèké láàrin ara wọn. Èyí yóo mú kí ó rọ̀ ọ́ lọ́rùn, wọn yóo sì máa bá ọ gbé ninu ẹrù náà.

23. Bí Ọlọrun bá gbà fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀, tí o sì ṣe é, ẹ̀mí rẹ yóo gùn, gbogbo àwọn eniyan wọnyi náà yóo sì pada sí ilé wọn ní alaafia.”

24. Mose gba ọ̀rọ̀ tí baba iyawo rẹ̀ sọ, ó sì ṣe gẹ́gẹ́ bí ìmọ̀ràn tí ó fún un.

25. Mose yan àwọn ọkunrin tí wọ́n lè ṣe alákòóso ninu àwọn eniyan Israẹli, ó fi wọ́n ṣe olórí àwọn eniyan náà, àwọn kan jẹ́ alákòóso fún ẹgbẹẹgbẹrun eniyan, àwọn mìíràn, fún ọgọọgọrun-un eniyan, àwọn mìíràn, fún araadọta, àwọn mìíràn fún eniyan mẹ́wàá mẹ́wàá.

26. Wọ́n ń ṣe ìdájọ́ àwọn eniyan náà nígbà gbogbo; àwọn ọ̀rọ̀ tí ó bá fẹ́ díjú nìkan ni wọ́n ń kó tọ Mose lọ, wọ́n ń yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèké láàrin ara wọn.

27. Mose gbà fún baba iyawo rẹ̀ pé kí ó máa pada lọ sí ìlú rẹ̀, baba iyawo rẹ̀ gbéra, ó sì pada sí orílẹ̀-èdè rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 18