Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 18:1-16 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Jẹtiro, alufaa àwọn ará Midiani, baba iyawo Mose, gbọ́ gbogbo ohun tí Ọlọrun ti ṣe fún Mose ati fún Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀, ati bí ó ti mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Ijipti.

2. Jẹtiro, baba iyawo Mose mú Sipora aya Mose, lẹ́yìn tí Mose ti dá a pada sọ́dọ̀ baba rẹ̀ tẹ́lẹ̀,

3. ati àwọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin mejeeji. Orúkọ ọmọ rẹ̀ kinni ni Geriṣomu, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Mo ti jẹ́ àtìpó ní ilẹ̀ àjèjì.”)

4. Orúkọ ọmọ keji ni Elieseri, (ìtumọ̀ rẹ̀ ni pé, “Ọlọrun baba mi ni olùrànlọ́wọ́ mi, òun ni ó sì gbà mí kúrò lọ́wọ́ idà Farao.”)

5. Jẹtiro, baba iyawo Mose, mú iyawo Mose, ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji tọ̀ ọ́ wá ní aṣálẹ̀, níbi tí wọ́n pàgọ́ sí níbi òkè Ọlọrun.

6. Nígbà tí wọ́n sọ fún Mose pé Jẹtiro, baba iyawo rẹ̀, ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀ pẹlu iyawo rẹ̀ ati àwọn ọmọ rẹ̀ mejeeji,

7. Mose lọ pàdé wọn, ó wólẹ̀ níwájú Jẹtiro, ó fi ẹnu kò ó lẹ́nu, wọ́n bèèrè alaafia ara wọn, wọ́n sì wọ inú àgọ́ lọ.

8. Gbogbo ohun tí Ọlọrun ṣe sí Farao ati sí àwọn ará Ijipti nítorí àwọn ọmọ Israẹli ni Mose ròyìn fún baba iyawo rẹ̀. Ó sọ gbogbo ìṣòro tí wọ́n rí lójú ọ̀nà, ati bí OLUWA ti kó wọn yọ.

9. Jẹtiro sì bá wọn yọ̀ nítorí gbogbo oore tí OLUWA ti ṣe fún àwọn ọmọ Israẹli, nítorí gbígbà tí ó gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti.

10. Jẹtiro dáhùn, ó ní, “Ẹni ìyìn ni OLUWA, tí ó gbà yín kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti ati lọ́wọ́ Farao.

11. Mo mọ̀ nisinsinyii pé OLUWA ju gbogbo àwọn oriṣa lọ, nítorí pé ó ti gba àwọn eniyan náà lọ́wọ́ àwọn ará Ijipti, nígbà tí àwọn ará Ijipti ń lò wọ́n ní ìlò àbùkù ati ẹ̀gàn.”

12. Jẹtiro bá rú ẹbọ sísun sí Ọlọrun. Aaroni ati àwọn àgbààgbà Israẹli sì wá sọ́dọ̀ Jẹtiro, láti bá a jẹun níwájú Ọlọrun.

13. Ní ọjọ́ keji, Mose jókòó, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìdájọ́ fún àwọn ọmọ Israẹli, àwọn eniyan wà lọ́dọ̀ rẹ̀ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́.

14. Nígbà tí baba iyawo Mose rí gbogbo ohun tí Mose ń ṣe fún àwọn eniyan, ó pè é, ó ní, “Kí ni gbogbo ohun tí ò ń ṣe fún àwọn eniyan wọnyi? Kí ló dé tí o fi wà lórí àga ìdájọ́ láti òwúrọ̀ títí di àṣáálẹ́, tí àwọn eniyan ń kó ẹjọ́ wá bá ìwọ nìkan?”

15. Mose dáhùn pé, “Ọ̀dọ̀ mi ni àwọn eniyan náà ti máa ń bèèrè ohun tí Ọlọrun fẹ́ kí wọ́n ṣe.

16. Nígbà tí èdè-àìyedè bá wà láàrin àwọn aládùúgbò meji, èmi ni mo máa ń parí rẹ̀ fún wọn. Èmi náà ni mo sì máa ń sọ òfin Ọlọrun, ati àwọn ìpinnu rẹ̀ fún wọn.”

Ka pipe ipin Ẹkisodu 18