Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 16:16-25 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Àṣẹ tí OLUWA pa ni pé, ‘Kí olukuluku yín kó ìwọ̀nba tí ó lè jẹ tán, kí ẹ kó ìwọ̀n Omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àgọ́ yín.’ ”

17. Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó.

18. Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ.

19. Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.”

20. Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn.

21. Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù.

22. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose,

23. ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ”

24. Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin.

25. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 16