Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkisodu 16:14-27 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nígbà tí ìrì náà kásẹ̀ nílẹ̀, wọ́n rí i tí kinní funfun kan tí ó dàbí ìrì dídì bo ilẹ̀ ní gbogbo aṣálẹ̀ náà.

15. Nígbà tí àwọn eniyan Israẹli rí i, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí bi ara wọn léèrè pé, “Kí nìyí?” Nítorí pé, wọn kò mọ ohun tíí ṣe.Mose bá dá wọn lóhùn pé, “Oúnjẹ tí OLUWA fún yín láti jẹ ni.

16. Àṣẹ tí OLUWA pa ni pé, ‘Kí olukuluku yín kó ìwọ̀nba tí ó lè jẹ tán, kí ẹ kó ìwọ̀n Omeri kan fún ẹnìkọ̀ọ̀kan ninu àgọ́ yín.’ ”

17. Àwọn eniyan Israẹli sì ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn mìíràn kó ju ohun tí ó yẹ kí wọ́n kó, àwọn mìíràn kò sì kó tó.

18. Ṣugbọn nígbà tí wọn fi ìwọ̀n Omeri wọ̀n ọ́n, àwọn tí wọ́n kó pupọ jù rí i pé, ohun tí wọ́n kó, kò lé nǹkankan; àwọn tí wọn kò sì kó pupọ rí i pé ohun tí wọ́n kó tó wọn; olukuluku kó ìwọ̀n tí ó lè jẹ.

19. Mose wí fún wọn pé, “Kí ẹnikẹ́ni má ṣe ṣẹ́ ohunkohun kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji.”

20. Ṣugbọn wọn kò gbọ́rọ̀ sí Mose lẹ́nu; àwọn mìíràn ṣẹ́ ẹ kù di òwúrọ̀ ọjọ́ keji, nígbà tí ilẹ̀ ọjọ́ keji mọ́, ohun tí wọ́n ṣẹ́kù ti bẹ̀rẹ̀ sí yọ ìdin, ó sì ń rùn, Mose bá bínú sí wọn.

21. Ní àràárọ̀ ni olukuluku máa ń kó ohun tí ó bá lè jẹ tán, nígbà tí oòrùn bá gòkè, gbogbo èyí tí ó bá wà nílẹ̀ yóo sì yọ́ dànù.

22. Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹfa, wọ́n kó ìlọ́po meji, olukuluku kó ìwọ̀n Omeri meji meji. Nígbà tí àwọn àgbààgbà Israẹli lọ sọ fún Mose,

23. ó wí fún wọn pé, “Ohun tí OLUWA wí nìyí, ‘Ọ̀la ni ọjọ́ ìsinmi tí ó ní ọ̀wọ̀, ọjọ́ ìsinmi mímọ́ fún OLUWA. Ẹ dín ohun tí ẹ bá fẹ́ dín, kí ẹ sì se ohun tí ẹ bá fẹ́ sè, ohun tí ó bá ṣẹ́kù, ẹ fi pamọ́ títí di òwúrọ̀ ọ̀la.’ ”

24. Wọ́n bá fi ìyókù pamọ́ títí di òwúrọ̀ gẹ́gẹ́ bí Mose ti sọ fún wọn; kò sì rùn, bẹ́ẹ̀ ni kò yọ ìdin.

25. Mose wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ èyí lónìí, nítorí pé òní ni ọjọ́ ìsinmi OLUWA, ẹ kò ní rí kó rárá ní òní.

26. Ọjọ́ mẹfa ni ẹ óo fi máa rí oúnjẹ kó, ṣugbọn ní ọjọ́ keje tíí ṣe ọjọ́ ìsinmi, kò ní sí níbẹ̀ rárá.”

27. Ní ọjọ́ keje, àwọn mìíràn ninu àwọn eniyan náà jáde láti lọ kó oúnjẹ, ṣugbọn wọn kò rí ohunkohun.

Ka pipe ipin Ẹkisodu 16