Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 4:11-22 BIBELI MIMỌ (BM)

11. “Lẹ́yìn náà, ẹ súnmọ́ òkè náà, nígbà tí ó ń jóná, tóbẹ́ẹ̀ tí ahọ́n iná náà fẹ́rẹ̀ kan ojú ọ̀run, tí òkùnkùn ati ìkùukùu bo òkè náà.

12. Ọlọrun ba yín sọ̀rọ̀ láti inú iná náà wá, ẹ gbọ́ ohùn rẹ̀, ṣugbọn ẹ kò rí i. Ohùn rẹ̀ nìkan ni ẹ̀ ń gbọ́.

13. Ó sọ majẹmu rẹ̀ fun yín, tíí ṣe àwọn òfin mẹ́wàá tí ó pa láṣẹ fun yín láti tẹ̀lé, ó sì kọ wọ́n sí orí tabili òkúta meji.

14. OLUWA pàṣẹ fún mi nígbà náà, láti kọ yín ní ìlànà ati òfin rẹ̀, kí ẹ lè máa tẹ̀lé wọn ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà.

15. “Nítorí náà, ẹ ṣọ́ra gidigidi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ kò rí ìrísí OLUWA ní ọjọ́ tí ó ba yín sọ̀rọ̀ láàrin iná ní Horebu,

16. ẹ ṣọ́ra kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀ nípa yíyá ère fún ara yín, irú ère yòówù tí ó lè jẹ́; kì báà ṣe akọ tabi abo,

17. yálà àwòrán ẹrankokẹ́ranko tí ó wà ní orílẹ̀ ayé, tabi àwòrán ẹyẹkẹ́yẹ tí ń fò lójú ọ̀run,

18. kì báà ṣe àwòrán ohunkohun tí ń rìn lórí ilẹ̀, tabi àwòrán ẹjakẹ́ja tí ń bẹ ninu omi.

19. Ẹ ṣọ́ra nígbà tí ẹ bá gbé ojú yín sókè sí ojú ọ̀run, tí ẹ bá rí oòrùn, òṣùpá, ati àwọn ìràwọ̀, ati ogunlọ́gọ̀ àwọn ohun tí ó wà ní ojú ọ̀run, kí ọkàn yín má baà fà sí wọn, kí ẹ sì máa bọ àwọn ohun tí OLUWA Ọlọrun yín fún gbogbo eniyan láyé.

20. Ọlọrun ti yọ yín kúrò ní ilẹ̀ Ijipti, ilẹ̀ tí ó dàbí iná ìléru ńlá, ó ko yín jáde láti jẹ́ eniyan rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti jẹ́ lónìí.

21. Nítorí tiyín gan-an ni OLUWA ṣe bínú sí mi, tí ó sì fi ibinu búra pé, n kò ní kọjá sí òdìkejì Jọdani, n kò sì ní dé ilẹ̀ dáradára náà, tí OLUWA Ọlọrun yín fun yín.

22. Nítorí náà, mo níláti kú ní ìhín yìí, n kò gbọdọ̀ rékọjá sí òdìkejì Jọdani, ṣugbọn ẹ̀yin óo rékọjá sí òdìkejì rẹ̀, ẹ óo sì gba ilẹ̀ dáradára náà.

Ka pipe ipin Diutaronomi 4