Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 34:7-12 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Mose jẹ́ ẹni ọgọfa (120) ọdún nígbà tí ó kú, ojú rẹ̀ kò ṣe bàìbàì, bẹ́ẹ̀ ni agbára rẹ̀ kò dínkù.

8. Àwọn ọmọ Israẹli ṣọ̀fọ̀ Mose fún ọgbọ̀n ọjọ́ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Moabu, wọ́n sì parí ṣíṣe òkú rẹ̀.

9. Joṣua ọmọ Nuni kún fún ọgbọ́n nítorí pé Mose ti gbé ọwọ́ rẹ̀ lé e, nítorí náà àwọn ọmọ Israẹli ń gbọ́ tirẹ̀, wọ́n sì ń ṣe gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí OLUWA pa fún Mose.

10. Láti ìgbà náà, kò tíì sí wolii mìíràn ní ilẹ̀ Israẹli tí ó dàbí Mose, ẹni tí Ọlọrun bá sọ̀rọ̀ lojukooju.

11. Kò sì sí ẹlòmíràn tí OLUWA rán láti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lára Farao ati gbogbo àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati gbogbo ilẹ̀ rẹ̀, ní ilẹ̀ Ijipti.

12. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí wolii mìíràn tí ó ní agbára ńlá tabi tí ó ṣe àwọn ohun tí ó bani lẹ́rù bí Mose ti ṣe lójú gbogbo àwọn ọmọ Israẹli.

Ka pipe ipin Diutaronomi 34