Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Diutaronomi 33:26-29 BIBELI MIMỌ (BM)

26. Ẹ̀yin ará Jeṣuruni,kò sí ẹni tí ó dàbí Ọlọrun yín,tí ó gun awọsanma lẹ́ṣin ninu ọlá ńlá rẹ̀,láti wá ràn yín lọ́wọ́.

27. Ọlọrun ayérayé ni ààbò yín,ọwọ́ rẹ̀ ni ó sì fi ń gbé yín ró.Bí ẹ ti ń súnmọ́ wájú,bẹ́ẹ̀ ni ó ń lé àwọn ọ̀tá yín jáde,tí ó sì ní kí ẹ máa pa wọ́n run.

28. Nítorí náà, Israẹli wà ní alaafia,àwọn ọmọ Jakọbu sì ń gbé láìléwu,ní ilẹ̀ tí ó kún fún ọkà ati ọtí waini,tí ìrì sì ń sẹ̀ sórí rẹ̀ láti ọ̀run wá.

29. Ẹ máa fò fún ayọ̀, ẹ̀yin ọmọ Israẹli,ta ló tún dàbí yín,ẹ̀yin orílẹ̀-èdè tí OLUWA tìkalárarẹ̀ gbàlà?OLUWA tìkalárarẹ̀ ni ààbò yín, ati idà yín,òun ní ń dáàbò bò yín, tí ó sì ń fun yín ní ìṣẹ́gun.Àwọn ọ̀tá yín ni yóo máa wá bẹ̀bẹ̀ fún àánú,ẹ óo sì máa tẹ àwọn pẹpẹ ìrúbọ wọn mọ́lẹ̀.

Ka pipe ipin Diutaronomi 33